Categories
Ìròyìn

Ìjọba Èkó Ti Ti Ọ̀nà Pápá Ìṣeré Teslim Balógun Pa Fún Ìdíje Super Eagles

YBTC News YORÙBÁ— Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti pinnu láti ti ònà ti ó wọ pápá ìṣeré Teslim Balógun pa àti láti má gba àwọn ọkọ̀ láàyè láti kọjá fún ìdíje komẹṣẹ̀-yọ láárin agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàíjíríà àti Lesotho. Nígbà tí olùdarí ikọ̀ tó ń rí sí ètò ìrìnnà ìpínlẹ̀ náà ń sọrọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Frederic Oladeinde, […]

Categories
Ìròyìn

Tinúbú Ló Pegedé Jùlọ Láti Jẹ Ààrẹ Nàíjíríà – Doyin Okupe

YBTC News YORÙBÁ— Doyin Okupe, abẹ́sinkáwọ́ ààrẹ orilẹ èdè Nàìjíríà nígbà kan rì, Goodluck Ebele Jonathan ti fi èrò ọkàn rẹ̀ hàn nípa èròngbà Tinúbú fún ipò ààrẹ ọdún 2023. Okupe ní Asíwájú Tinúbú, ọ̀kan nínú àwọn àgbà ẹgbẹ́ APC, ní ẹni tí ò pegedé, tì ó sì kájú òṣùwọ̀n jùlọ nínú gbogbo àwọn tí […]

Categories
Ìròyìn

Ìbẹ̀rù Bo Ọ̀ṣun, Ènìyàn Mẹ́ta Kú Níbi Ìkọlù Àwọn Ẹlẹ́gbẹ́ Òkùnkùn

YBTC News YORÙBÁ— Ènìyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù láàrin àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ní agbègbè Kọ́láwọlé, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Èyí sì ti fa inú-fu-àyà-fu láàrin àwọn ènìyàn. Ìròyìn fi tó wa létí pé ìkọlù náà wáyé láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aiye ati ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ àáké. Wọ́n ń jà fún ìfagagbága […]

Categories
Ìròyìn

Okọ̀ Àjàgbé Nla Tẹ Eniyan Mẹ́ta Pa Ní Ògùn

YBTC News YORÙBÁ—  Ènìyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti gbẹ́mí mì níbi ìjànbá ojú pópó tí ó ṣẹ̀lẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì. Ọkọ̀ Àjàgbé ńlá kan àti alupùpù ni o wà nínú ìjànbá náà ní Abẹ́òkúta. Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ tí ó ń rí sí ìtẹ̀lé ìgbòkè gbodò ojú pópó, Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Akínbìyí fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ […]

Categories
Ìròyìn

UI Ti Kéde Ọjọ́ Ìdánwò PUTME Wọn

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn aláṣẹ yunifásítì Ìbàdàn ti kéde ọjọ́ tí ilé ìwé gíga náà yóò ṣe ìdánwò àṣewọlé sí ilé ìwé náà. Ní òwúrọ̀ òní ọjọ Ẹtì ni ẹka ìbánisọ̀rọ̀ ọ́fíìsì ọ̀gá ilé ìwé náà kéde ọjọ́ ìdánwò PUTME. Wọ́n si jẹ́ kí á mọ̀ wípé ìdánwò ayára bí àṣá (CBT) ni wọn yóò […]

Categories
Ìròyìn

Ẹka ASUU Ti Ìpínlẹ̀ Ẹdo Gùn Lé Ìyanṣẹ́ Lódì

YBTC News YORÙBÁ— Ìpín kan nínú àjọ ASUU ti ìpínlẹ̀ Edo yóò gùn lé ìyanṣẹ́ lódì lóní ọjọ́’bọ̀. Ìkéde yìí wáyé láti ẹka ASUU ti Yunifásitì Ambrose Alli, Ekpoma, ní ìpínlẹ̀ Edo. Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀wẹ̀, àjọ mìíràn tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga náà, CONUA, ti takò ìgbésẹ yìí, wn sì […]

Categories
Ìròyìn

Ìyàwó Mi Ń Fi Ìbálòpọ̀ Jẹ mí Níyà. Ọkọ Ìyàwó Ké Lọ Ilé Ẹjọ́

YBTC News YORÙBÁ—  Arákùnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tíì lọ jù, Joseph Manya, ní òní Ọjọ́’rú, ló ti ké gbàjarè lọ sí ilé ẹjọ́ abẹ́lé Kafanchan ní ìpínlẹ̀ Kaduna wípé kí wọn ya àwọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nítorí oorun. Manya sọ pé ìyàwó òun, Patience kìí gbà kí òun báa lájọsepọ̀. Bákan náà ni ó […]