Categories
Ìròyìn

Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ (Lassa Fever) Tuntun Ṣẹ́yọ Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

YBTC News Yoruba—Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kaduna, ìyẹn Dókítà Amina Mohammed-Baloni ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ àbàmẹ́ta wípé ibà ìrẹ̀lẹ̀ tí gbogbo wa mọ̀ sí Lassa Fever tún ti ṣẹ́ yọ ní ìpínlẹ̀ náà. Komíṣọ́nà náà sọ wípé arákùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún ni ó ní àrùn náà, […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbé’bọnrìn Jí Ẹ̀ṣọ́ Tó Ń Rí Sí Ìkó Ẹrù Òfin Wọ’lẹ̀ Yìí Mẹ́rin Gbé Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

YBTC Yorùbá- Ìròyìn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn Afurasí Agbé’bọnrìn ti jí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹ́ṣọ̀ọ́ tí ó ń rí sí kíkó ẹrú wọn orílẹ̀ èdè yìí mẹ́rin, ìyẹn òṣìṣẹ́ Nigerian Custom Service. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Jibia ní ìpínlẹ̀ Katsina tí ó jẹ́ ìlú Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Ààrẹ Muhammadu Buhari. […]

Categories
Ìròyìn

Ó Ti Di Ènìyàn Mẹ́fà Tí ó Ti Jẹ́ Ọlọ́run Nípè Nínú Afẹ́fẹ́ Gáàsì Ìdáná Tí ó Gbaná Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

YBTC Yorùbá- Ó kéré tán, ènìyàn mẹ́fà ti jẹ́ Ọlọ́run nípè nínú ìṣẹ̀lẹ̀ iná afẹ́fẹ́ gáàsà tí ó gbaná ní ìpínlẹ̀ Kaduna ní ọjọ́ àbàmẹ́ta ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá. Olú ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn oníròyìn létí nínú àtẹ̀jáde tí ó fi léde ní ọ̀sán ọjọ́ ajé. Afẹ́fẹ́ ìdáná náà […]

Categories
Ìròyìn

Hílàhílo Rọ́lu Ìpínlẹ̀ Kaduna Bí Àwọn Ọmọdé Mẹ́ta Ṣe Di Gbígbésin Láàyẹ̀

YBTC Yorùbá -Hílàhílo rọ́lu àwọn ará àdúgbò Rigasa ní Ìpínlè Kaduna ní òní Ọjọ́bọ bí àwọn ọmọdé mẹ́ta ṣe di gbígbésin láàyè. Ìròyìn fi ìdí rẹẹ̀ lélẹ̀ wípé iyẹ̀pẹ̀ ni ó dà lé wọn lórí ni wọ́n bá gbé ẹ̀mí míì. Olórí Ìmáàmù Mọṣáláṣí Jímọ̀ ti Kalshen Kwalta, Malam Jamilu fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún […]