Categories
Eré Ìdárayà

Rohr Kọ̀wẹ́ Pe Desser àti Ehizibue Láti Gbá Bọ́ọ́lù Fún Ikọ̀ Super Eagles Nígbà Àkọ́kọ́

YBTC News Yorùbá-Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ Super Eagles, ìyẹn Germot Rohr ti kọ̀wẹ́ pe agbábọ́ọ̀lú nípò ẹ̀yìn fún ikọ̀ FC Koln ìyẹn Kingsley Ehizibue àti agbábọ́ọ̀lú nípò iwájú fún ikọ̀ Heracles, ìyẹn Cyriel Desser láti wá gbá bọ́ọ́lù fún orílẹ̀ èdè abínibí wọn fún ìgbà àkọ́kọ́. Ikọ̀ Super Eagles yóò wá kò pẹ̀lú Ikọ̀ Leone Stars […]

Categories
Eré Ìdárayà

Wọ́n Fi Òfin De Daniel Sturridge Bí ó Tasẹ̀ Àgẹ̀ẹ̀rẹ̀ Sí Òfin Tẹ́tẹ́ Ní Orílẹ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì

YBTC News Yoruba—Àjọ tí ó ń rí sí ètò bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí a mọ̀ sí FA ti fi òfin dé Daniel Sturridge káàkiri àgbáyé pẹ̀lú owó ìtànnà tó ń lọ bi ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà Ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́ta owó ilẹ̀ aláwò funfun, ìyẹn 150,000 Europe. Sturridge tí ó jẹ́ ọmọ àádọ́ta […]

Categories
Eré Ìdárayà

Nemanja Metic Yóò Fi Ikọ̀ Manchester United Sílẹ̀ Lópin Sáà Igbábọ́ọ́lù Yìí

YBTC News Yorùbá-Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, gbajúgbajà ọmọ ilẹ̀ Serbia tí ó ń gbá bọ́ọ́lù jẹun ní ikọ̀ Manchester United ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò fi Ikọ̀ náà sílẹ̀ lópin sáà igbábọ́ọ́lù yìí nígbà tí àdéhùn rẹ̀ pẹ̀lú Ikọ̀ náà yóò dópin. Metic kò ráyè gbá bọ́ọ́lù dáadáa lábẹ́ Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester […]

Categories
Eré Ìdárayà

Guardiola Ṣetán Láti Wà Pẹ̀lú Ikọ̀ Man City Pẹ̀lú Bí Wọ́n Ṣe Fòfin De Ikọ̀ Náà

YBTC News Yorùbá- Pep Guardiola ti sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ àti olólùfẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ajé wípé òun yóò ma ṣe Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ Manchester City, kódà kí ẹjọ́ tí Ikọ̀ náà tún pè kò bá gbé Ikọ̀ náà. Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá ọmọ ọdún kọkàndínláàdọ́ta tí ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Spain sọ fún àwọn aláṣẹ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Son Gbọn Omi Ewúro Sí Aston Villa Lójú Lẹ́yìn Ìkùlé Wọn Bí ó Ṣe Kú Díẹ̀ Kí Ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ Wọ́n Wà Sí Òpin

YBTC News Yorùbá-Heung-Min Son gbógo fún ikọ̀ Tottenham Hostspur nínú ìdíje àgbákuta líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọjọ́ àìkú bí ó ṣe ku díẹ̀ kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí ó wáyé láàárín Ikọ̀ náà àti Ikọ̀ Aston Villa wá sópin. Son tí ó gbá bọ́ọ́lù sáwọ̀n fún ikọ̀ Tottenham Hostspur bí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ṣe ń wá sí òfin […]

Categories
Eré Ìdárayà

Óṣeéṣe Kí Aaron Ramsey Padà Sí Ikọ̀ Arsenal

YBTC Yorùbá—Ìyàlẹ́nu ni yóò jẹ̀ẹ́ nígbàtí Ikọ̀ Arsenal bá fìpinnu wọn hàn láti ra Aaron Ramsey padà sí Ikọ̀ Arsenal lẹ́yìn tí agbábọ́ọ̀lú Arsenal tẹ́lẹ̀ rí náà tí ń gbìyànjú láti rí bọ́ọ́lù gbá ní ikọ̀ Juventus ní orílẹ̀ Ìtàló lọ́ùń. Ìfarapa ti ṣe ìfàsẹ́hìn fún Ramsey láti ìgbà tí ó ti darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ Kejìlélógún Rèé Tí Ahmed Musa Tigbá Bọ́ọ́lù Sáwọ̀n Gbẹ̀yìn

YBTC Yorùbá- Balógun Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Super Eagles, Ahmed Musa tí ó ń tún gbá bọ́ọ́lù jẹun ní ikọ̀ Al Nassr ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia ti kùnà láti tún gbá bọ́ọ́lù sáwọ̀n fún ikọ̀ rẹ̀ nínú ìdíje àgbákuta líígì ilẹ̀ Saudi. Nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ tí Ikọ̀ rẹ̀ ti kojú Ikọ̀ Al Fateh FC ni wọ́n gbá […]

Categories
Eré Ìdárayà

Barcelona, Real Madrid Tí ń Gbìyànjú Láti Tọwọ́ Osimhen Bọ̀wé

YBTC Yorùbá-Òye tí ń fojú hàn báyìí wípé àwọn Orogún méjèèjì nínú ìdíje líígì ilẹ̀ Spain, ìyẹn Ikọ̀ Barcelona àti Ikọ̀ Real Madrid tí ń jà fitafita láti tọwọ́ agbábọ́ọ̀lú Ikọ̀ Lille, Victor Osimhen bọ̀wẹ́ bí sáà igbá bọ́ọ́lù míì ṣé ń fojú hàn. Ikọ̀ méjèèjì ni wọ́n tí ń gbìyànjú láti ṣà lékún agbára […]

Categories
Eré Ìdárayà

Arsene Wenger Ṣe Ìfilọ́lẹ̀ Ètò Ṣíṣe Àwárí Ẹ̀bùn Fún Ìdàgbàsókè Ti Àjọ FIFA Gbékalẹ̀

Àjọ tí ó ń rí sí ètò bọ́ọ́lù gbígbá lágbàyé, ìyẹn FIFA ti kéde ìfilọ́lẹ̀ ètò kan tí ó pè ní ṣíṣe àwárí ẹ̀bùn tí ó yanrantí fún ìdàgbàsókè, tí Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ sì jẹ́ “groundbreaking talent development programme”. Ìpínnu FIFA ni láti dín ààyè tí ó má ń ṣí sílẹ̀ láárí àwọn orílẹ̀ èdè tí […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Arsenal Tí ń Gbìyànjú Láti Kówólé Agbábọ́ọ̀lù Àdehìnmú Flamingo Bí Iná Ikọ̀ Náà Ṣe ń Jó Àjórẹ̀hìn

YBTC Yorùbá- Arsenal ń gbìyànjú láti tọwọ́ agbábọ́ọ̀lú Flamingo tí ó jẹ́ Àdehìnmú fún ikọ̀ náà, ìyẹn Pablo Mari bí ó ṣeéṣe kí agbábọ́ọ̀lú náà má padà sí orílẹ̀ èdè Brazil. Mari wá sí ìlú Olú ìlú ilé Gẹ̀ẹ́sì, London fún Àyẹ̀wọ̀ ìlera ara rẹ̀ ní ikọ̀ Arsenal. Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ wípé Ikọ̀ Arsenal […]