Categories
Ìròyìn

El-Rufai Sọ Pé Tí Àwọn Ajínigbé Bá Gbé Ọmọ Òun Gan, Òun Ò Ní Sanwó

YBTC News YORÙBÁ— Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam El-Rufai sọ pé òun kò níí san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé kódà tí wọn bá gbé ọmọ bíbí inú òun. El-Rufai sọ èyí di mímọ̀ nínú ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ lórí rẹ́díò ní òní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìṣèjọba òun kò fi àyè sílẹ̀ fún […]

Categories
Ìròyìn

Wọ́n Ti Rí Àwọn Ọmọ Ìjọ RCCG Mẹ́jọ Tí Wọ́n Gbé

YBTC News YORÙBÁ— Alámójútó gbogbo-gbò fún ìjọ RCCG, Enoch Adeboye ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ìjọ mẹ́jọ tí wọn kó ní ọ̀ṣẹ̀ tó lọ ti rí ìtúsílẹ̀. Àwọn ọmọ ìjọ tí wọn kó ọ̀ún ni wọ́n gbé ní ọ̀nà Kachia-Kafanchan nínú ọkọ̀ ìjọ nígbà tí wọ́n ń lọ sí ilé […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbébọn Tún Ti Gbé Òṣìṣẹ́ Kùsà Mẹ́ta Ní Ìbàdàn

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn agbébọn kan tí a fura sí gẹ́gẹ́ bí gbọ́mọgbọ́mọ ti ṣe ìkọlù sí àyè ìwakùsà kan ní ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Wọ́n kó ènìyàn mẹ́ta lọ. Orúkọ àyé ìwakùsà yìí ni Megabolex Quarry, ní ìdí Ayunre, ní ọ̀nà Ibadan-Ìjẹ̀bú Òde ní ìjọba ìbílẹ̀ Oluyole. Ní déédé aago mẹ́rin-àbọ̀ ọ̀sán ni wọ́n gbé […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbébọn Pa Alága PDP Tẹ́lẹ̀, Wọ́n Gbé Ìyàwó Rẹ̀ Lọ

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn agbébọn kan ti pa alága ẹgbẹ́ PDP nígbà kan rí Sule Ishaya, ní ìjọba ìbílẹ̀ Tafa ní ìpínlẹ̀ Niger. Bákan náà ni wọn tún gbé ìyàwó rẹ̀ lọ. Ní alẹ́ ni àwọn agbébọn ọ̀ún ya wọ ilé Ishaya ni agbègbè New Bwari. Wọ́n gún un ní ọ̀bẹ àyà kí wọn tó […]

Categories
Ìròyìn

Ọlọ́pàá Ti Dóòlà Ẹni Ti Wọn Gbé Ní Ọ̀ṣun

YBTC News YORÙBÁ— Àbúrò Sarkin Hausa tí ó ń jẹ́ Usman, tí àwọn afurasí ajínigbé gbé lọ ní Oṣú, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni won ti fi sílẹ̀. Usman pẹ̀lú àwọn méjì kan ni wọn wà nínú ọkọ ní ọ̀nà  Ife/Osu/Ibodi kí àwọn ajínigbé tó ó dáwọn lọ́nà ní ọjọ́’bọ̀. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, […]

Categories
Ìròyìn

Wọ́n Ti Bèèrè Fun N50m Owó Ìtúsílẹ̀ Àwọn Ọmọ Ìjọ RCCG

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ tí ìròyìn gbé wípé àwon ajínigbé agbébọn gbé ni a gbọ́ wípé wọn ti bèèrè owó tó tó N50m láti fi tú wọn sílẹ̀. Olórí àgbà ijọ́ náà kan tí ó jẹ́rí sí ìlè àwọn ajínigbé yìí àti iye owó tí wọn bèèrè . Ó sàlàyé wípé […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbébọn Ti Gbé Ọba Àlàyé Kan Ní Ògùn

YBTC News YORÙBÁ—  Ọba Tajudeen Ọmọ́táyọ̀, Ọba Aládé-Mẹ́ta ti Ilẹ̀ Imope, ti agbègbè, Ìjẹ̀bú-Igbó, ìpínlẹ̀ Ògùn ni àwọn agbébọn tí a ò tíì mọ̀ ti gbé lọ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta. Ìròyìn jẹ́ kí á mọ̀ pé ọba alayé náà kúrò ní ààfin rẹ ní déédé aago mọ́kànlá òwúrọ̀ pẹlú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ olú nọ́ḿbà ìdánimọ̀ […]