Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àjọ CAN Sẹ́ Àlùfáà Ìjọ Tí Ọmọ Ọdún Kan Pòórá Ní Ilé Ìjọsìn Rẹẹ̀

YBTC Yorùbá – Ẹgbẹ́ ọmọ lẹ́yìn Krìstẹ́nì ilẹ̀ Nàìjíríà ìyẹn CAN ti Ìpínlẹ̀ Ondó ti sẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣi Sotitobire. Olórí Àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Ondó, Ọmọwé John Ayò Oládàpọ̀ sọ wípé àlùfáà tí ọmọ ọdún kan déédéé pòórá nínu ṣọ́ọ̀ṣi rẹ̀ kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ CAN. Ní ọjọ́bo nígbà tí Oládàpọ̀ fojú-rinjú pẹ̀lú àwọn […]

Categories
Ìròyìn

Ọwọ́ Tẹ̀ẹ́! Ọwọ́ Tẹ Afurasí Tí Ó Ṣe Ikú Pa Òṣìṣẹ́ Àjọ NDLEA Méjì

YBTC Yorùbá – Àjọ tí ón rí sí fífi ọwọ́ ṣù kún òfin mú àwọn tí wọ́n ń gbé egbògi olóró ìyẹn cocain nílè Nàìjíríà ti fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú arákùnrin kan tí ó ṣe ikú pa òṣìṣẹ́ méjì àjọ náà ní oṣù kejì ọdún yìí. Ọ̀daràn náà tí a mọ̀ sí Ohimai Ayodele […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbé’bọnrìn Jí Alábiamọ Méjì Gbèé, Ọmọdé Mẹ́ta, Ṣe Ọlọ́pàá Mẹ́rin Léṣe Ní Ìpínlẹ̀ Adamawa

YBTC Yorùbá – Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ bíi kẹ̀lẹ̀bẹ̀ wèrè wípé àwọn agbé’bọnrìn kọlu àdúgbò kàn-án tí wọ́n ń pè ní Ganya ní ìjọba ìbílẹ̀ Ganya ní Ìpínlẹ̀ Adamawa lánàá. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù àná ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn agbé’bọnrìn ya wọ àdúgbò náà tí wọ́n sì jì í alábiamo méjì gbèé, wọ́n jí ọmọdé mẹ́ta nílé […]

Categories
Ìròyìn

Ènìyàn Mẹ́ta Ṣòfò Ẹ̀mí Nígbà Tí Ẹnìkan Farapa Yánayàna Nínú Jàm̀bá Ọkọ́ Ní Ojú na Márosẹ̀ Èkó Ṣí Abẹ́òkúta

YBTC Yorùbá -Àwọn Àjọ Ẹ̀ṣọ́ Ojú Pópó ìyẹn FRSC ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ògùn ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lónìí ọjọ́ etí wípé ènìyàn mẹ́ta ni ó jẹ́ ìpè Ọlọ́run ní ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ẹnìkan sì farapa yánayàna nínu jàm̀bá ọkọ̀ tí ó wáyé ní ojúnà Èkó sí Abẹ́òkúta. Ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé láàárín awakọ̀ alùpùpù ìyẹn […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àwọn Gómìnà Méjìlélógún Ni Wọ́n Ó Fi Ojú Ba Ilé-Ẹjọ́ – Malami

YBTC Yorùbá –Méjìlélógún gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ni wọn ó fi ojú ba ilé-ẹjọ́. Agbẹjọ́rọ̀ Àgbà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó tún jẹ́ Mínísítà Ètò Ìdájọ́, Ọ̀gbẹ́ni Abubakar Malami ní ó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà lélẹ̀ lánàá nígbà tí ó fi ojú-rinjú pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní ọ́ọ́fìsì rẹ̀. Ṣùgbọ́n Malami kò dárúkọ àwọn gómìnà àná […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari Bu’wọ́ Lu Ètò Ìsuná Ọdún 2020

by: Bada Yusuf –Ààrẹ Muhammadu Buhari Bu’wọ́ Lu Ètò Ìsuná Ọdún 2020 YBTC Yorùbá-Ààrẹ Muhammadu Buhari lánàá tí ń ṣe ọjọ́ ìṣẹ́gun bu’wọ́ lu ètò ìsuná ọdún 2020 ní ilé ìjọba àpapọ̀ ní olú ilẹ̀ wa ní Abuja. Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn Aṣòfin fi kún ìsuná náà láti 10.3 Trillion lọ sí 10.594 […]

Categories
Ìròyìn

Ilé Aṣòfin Àgbà Wọlé Ìjíròrò Lórí Owó Tí Buhari Fẹ́ Yá

YBTC Yorùbá-Ilé Aṣòfin Àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ti wọlé ìjíròrò lóri owó irànwọ́ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari fẹ́ yá láti ilẹ̀ òkèèrè lónìí tí ń ṣe ọjọ́ ìṣẹ́gun. Ìjọba Àpapọ̀ ní owó náà wà fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.  Lẹ́yìn tí olórí ọmọ ẹgbẹ́ tí ó pọ̀ jùlọ ní ilé Aṣòfin náà, Aṣòfin […]

Categories
Ìròyìn

Aláké Yóò Wọ Ìyá Ìjà Pẹ̀lú Ọlọ́tà Lóri Ọ̀rọ̀ Ilẹ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Ògùn

YBTC Yorùbá Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá, Ọba Adedotun Gbadebo yóò wọ kẹ̀nbẹ̀ ìjà pẹ̀lú Ọlọ́tà ti Ìlú Ọ̀tà, Ọ̀jọ̀gbọ̀n Abdulkabir Obalanlege lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ní Ìjú-Atana ní ìjọba ìbílẹ̀ Ado-Odò Ọ̀tà ni ìpínlè Ògùn.  Lẹ́yin ìlérí-leka tí ó ti wáyé láàárín àwọn Ọba méjèèjì, inu ìháhìlo ni àwọn ará àdúgbò tí ọ̀rọ̀ náà kàn wà. […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Arsenal Gba Àlejò Ọ̀ràn Lánàá, Mẹ́ta Sí Òdo Ni Ó jẹ Ní Ọwọ Man. City

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Arsenal fìdí rẹmi ní ilé wọn lánàá nígbà tí wọ́n gba ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Machester City ní àlejò nínú ìdíje líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àlùbámi ni àlejò Machester City náà fi onílé Arsenal ṣe nígbà tí ó báa lálejò ní pápá ìseré Emirate. Ayò mẹ́ta sí òdo ni Machester City fi ṣe ìyà fún Arsenal […]

Categories
Ìròyìn

“Unifásitì ti Abuja Ní Kí Professor Afìdí-Gba-Máàkì Méjì Lọ Rọ́ Kún’lé”

YBTC Yorùbá —Ilé ẹ̀kọ́ gíga unifásitì ti Ìlú Àbújá ti jáwèé gbélé ẹ lọ́wọ́ fún ò̀jọ̀gbọ́n méjì, ó sì tún já ipò Ọ́mọ́we méjì tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ nínu ọgbà ilé ìwé náà wálẹ̀. Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n méjì náà ni a fi ẹ̀sùn kàn wípé won a máa ní kí àwọn ọmọ obìnrin fi ẹ̀yìn wọn lélẹ̀ […]