Categories
Eré Ìdárayà

Àjọ CAF Gbọn Orúkọ Ọmọ Nàìjíríà Yọ Kúrò Nínú Àwọn Tí Yóò Figagbága Fún Àmì-Ẹ̀yẹ Ẹni Tó Mọ Bọ́ọ́lù Gbà Jùlọ Nílẹ̀ Aláwọ̀-dúdú Ní Ọdún 2019

Bada Yusuf YBTC Yorùbá-Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, kò sí orúkọ ọmọ Nàìjíríà kankan nínú àwọn tí yóò figagbága láti gba àmì-ẹ̀yẹ ẹni tí ó mọ bọ́ọ́lù gbá jùlo nílẹ̀ Áfíríkà bí Àjọ tó ń rí sí ètò bọ́ọ́lù nílẹ̀ Áfíríkà ìyẹn CAF ṣe kéde àwọn mẹ́ta kan lópin ọ̀sẹ̀. Àwọn mẹ́ta tí Àjọ CAF kéde náà […]

Categories
Ìròyìn

Ẹ Ṣọ́ra O! Ẹ Ṣọ́ra Fún Ẹran Màálù Àti Ti Àgùntàn Ní Jíjẹ Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ṣèkìlọ̀

YBTC Yorùbá-Ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ wa Nàìjíríà ti ṣe ìkìlọ̀ pàtàkì fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí pé kí wọ́n ṣọ́ra níbi jíjẹ ẹran màálù àti àgùntàn nítorí àìsàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn ní orílẹ̀ èdè Niger Republic. Nínú àtẹ̀jáde tí Àjọ ọ̀ún fi ránṣẹ́ síta, ó ṣe ìkìlọ̀ wípé àìsàn ọ̀ún […]

Categories
Ìròyìn

Buhari Fi Ọwọ́ Agbára Yọ Olùṣàkóso Ìfìwéránṣẹ́, Ó Yan Alága Míràn Fún Ìgbìmọ̀ Ètò Ìbánisọ̀rọ̀

Bada Yusuf YBTC Yorùbá—Ààrẹ Muhammadu Buhari ní àná ọjọ́ ajé bu’wọ́ lu ìyọ́ni nípò Olùṣàkóso Ìfìwéránṣẹ́ (NIPOST) àgbà ilẹ̀ yìí, nígbà tí ó yan alága mìíràn sí ipò Aláṣẹ Ìgbìmọ̀ Ètò Ìbánisọ̀rọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà. Ọ̀gbẹ́ni Bísí Adégbuyì ni Buhari yọ nípò nígbà tí Ọmọwé Ismail Adéwusì gbà’ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Bákan náà, ó bu’wọ́ lu ìyanni […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àwọn Ọlọ́pàá Gba Onídùúró Shina Peller, Wọ́n Ní Kí Ó Máa Lọ ‘Lè Ná

Bada Yusuf YBTC Yorùbá—Àjọ agbófinró ẹ̀ka tí ìpínlẹ̀ Èkó ti jọ̀wọ́ Aṣòfin ilẹ̀ wa kan tí wọ́n pè ní Shina Peller sílẹ̀ lẹ́yìn tí Onídùúró rẹ̀ ti yọjú. Àwọn agbófinró fi ẹ̀sùn kàn-án wípé Aṣòfin náà wípé ó kó jàndùkù wá sí ilè Ọlọ́pàá. Shina Peller jẹ́ Aṣòfin ni ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin kékeré ilẹ̀ wa […]

Categories
Ìròyìn

Ẹgbẹ́ A Já Fún Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn Pariwo Tantan Síta, Wọ́n Ní Àwọn Kò Sí Lára Àwọn Tó Fẹ́ Yọ Emir Ìlú Kano

YBTC Yorùbá-Ìpéjọ Àpapọ̀ Ẹgbẹ́ ọmọ a já fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Kano ti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú pípè fún ìyọ́ni kúrò nípò Emir ìlú Kano, ìyẹn Muhammad Sanusi II Nínú lẹ́tà tí àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà fi ránṣẹ́ sí Gómìnà Kano, Abdullahi Ganduje, wọ́n ní àwọn kò sí nínú ẹgbẹ́ a já […]

Categories
Ìròyìn

Ipa Tí Àwọn Obìnrin Ńkó Lágbo Òṣèlú Ju Ti Àwọn Ọkùnrin Lọ Igbá-kejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì

YBTC Yorùbá -Igbá-kejì Gómìnà ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, Olóyè Bísí Ẹgbẹ́yẹmí sọ fún àwọn oníròyìn lánàá wípé ipa tí àwọn obìnrin ń kó lágbo òṣèlú ju ti àwọn ọkùnrin lọ, ìyẹn bí a bá wo bí nǹkan ṣe rí lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí. Olóyè Ẹgbẹ́yẹmí wá mu dá àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ ọ̀ún lójú wípé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì […]

Categories
Ìròyìn àgbáyé

Agbẹjọ́rò Àgbà Àti Mínísítà Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Yìí Tẹ́lẹ̀ Rí Yóò Ṣe Ọdún Kérésìmesì Ní Akóló Àwọn EFCC

YBTC Yorùbá –Àjọ tó ń rí sí ìṣe owó ìlú mákumàku nílẹ̀ wa, ìyẹn EFCC ti gba ìwé àṣẹ ní ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ nílùú Abuja lánàá láti fi agbẹjọ́rò àgbà tí ó tún jẹ́ Mínísítà Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí Ọ̀gbẹ́ni Muhammed Bello Adoke sí Akóló rẹẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko. […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ǹkan Ò Ṣẹnure Fún Man. U: Ikọ̀ Watford Gbọn Ewúro Sí Wọn Lójú Lánàá

YBTC Yorùbá — Ǹkan ò ṣẹnure fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Machester United ní àná bí Ikọ̀ Watford tó wà ní ìsàlẹ̀ àtẹ líígì Gẹ̀ẹ́sì ṣe gbọn ewúro sí wọn lójú lánàá nínú ìdíje àtẹ líígì Gẹ̀ẹ́sì. Àmì ayọ̀ méjì sí òdo ni Watford fi gbẹ̀yẹ ní ọwọ Machester United.

Categories
Ìròyìn

Hílàhílo Rọ́lu Ìpínlẹ̀ Kaduna Bí Àwọn Ọmọdé Mẹ́ta Ṣe Di Gbígbésin Láàyẹ̀

YBTC Yorùbá -Hílàhílo rọ́lu àwọn ará àdúgbò Rigasa ní Ìpínlè Kaduna ní òní Ọjọ́bọ bí àwọn ọmọdé mẹ́ta ṣe di gbígbésin láàyè. Ìròyìn fi ìdí rẹẹ̀ lélẹ̀ wípé iyẹ̀pẹ̀ ni ó dà lé wọn lórí ni wọ́n bá gbé ẹ̀mí míì. Olórí Ìmáàmù Mọṣáláṣí Jímọ̀ ti Kalshen Kwalta, Malam Jamilu fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Aláàfin, Danjuma, Adébánjọ àti Àwọn Míràn Ṣe Àgbéyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Nàìjíríà Yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ Lánàá

YBTC Yorùbá – Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe Àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Nàìjíríà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ lánàá ní ibi ìfilọ́lẹ̀ ìwé kan ti ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Tribune ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ lánàá tí ń ṣe ọjọ́ bọ̀. Lára àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ náà ni ati rí Aláàfin Ikú Bàbá Yèyé Ọba Lamidi Adeyemi. Ọ̀gá Jagunjagun tẹ́lẹ̀ rí ní ilẹ́ Nàìjíríà, Ọ̀gágun Theophilus […]