Categories
Ìròyìn

Gùdùgbẹ̀ Já Lánàá Bí Àwọn Jàndùkú Agbé’bọnrìn Ṣe Kọlu Ilé Ààrẹ Àná Ní Ìlú Abínibí Rẹ̀

YBTC Yorùbá- Àwọn sùmọ̀ní Agbé’bọnrìn kọlu ilé Ààrẹ Àná ilẹ̀ wa, Olóyè Goodluck Jonathan ní ìlú abínibí rẹ̀. Buhari, Lawan, APC, PDP gbogbo wọn ni wọ́n bu ẹnu àtẹ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Wọ́n ní ẹ ṣe ìwádìí rẹ̀ dáadáa. Olobó láti ìlú Ààrẹ Àná náà tí ó ta àwọn oníròyìn lólobó sọ wípé ni déédéé […]

Categories
Ìròyìn

Kọmíṣọ́nà Méjì Kọ̀wé Fi Ipò Sílẹ̀ Lẹ́yìn Ọ̀sẹ̀ Méjì Tí Wọ́n Yàn Wọ́n Sípò

YBTC Yorùbá- Àwọn Kọmíṣọ́nà méjì ní ìpínlẹ̀ Zamfara ti kọ̀wẹ́ fi ipò wọn sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí Gómìnà Bello Matawalle yàn wọ́n sípò kọmíṣọ́nà. Láfikún, olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí Gómìnà tún kọ̀wẹ́ fi ipò rẹ̀ síẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n yan òun náà sípò Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ Alhaji Jamilu Zanna, Komíṣọ́nà fún Ètò-Ẹ̀kọ́ […]

Categories
Ìròyìn

Ẹ Ṣọ́ra O! Ẹ Ṣọ́ra Fún Ẹran Màálù Àti Ti Àgùntàn Ní Jíjẹ Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Ilẹ̀ Nàìjíríà Ṣèkìlọ̀

YBTC Yorùbá-Ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ wa Nàìjíríà ti ṣe ìkìlọ̀ pàtàkì fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí pé kí wọ́n ṣọ́ra níbi jíjẹ ẹran màálù àti àgùntàn nítorí àìsàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn ní orílẹ̀ èdè Niger Republic. Nínú àtẹ̀jáde tí Àjọ ọ̀ún fi ránṣẹ́ síta, ó ṣe ìkìlọ̀ wípé àìsàn ọ̀ún […]

Categories
Ìròyìn

Buhari Fi Ọwọ́ Agbára Yọ Olùṣàkóso Ìfìwéránṣẹ́, Ó Yan Alága Míràn Fún Ìgbìmọ̀ Ètò Ìbánisọ̀rọ̀

Bada Yusuf YBTC Yorùbá—Ààrẹ Muhammadu Buhari ní àná ọjọ́ ajé bu’wọ́ lu ìyọ́ni nípò Olùṣàkóso Ìfìwéránṣẹ́ (NIPOST) àgbà ilẹ̀ yìí, nígbà tí ó yan alága mìíràn sí ipò Aláṣẹ Ìgbìmọ̀ Ètò Ìbánisọ̀rọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà. Ọ̀gbẹ́ni Bísí Adégbuyì ni Buhari yọ nípò nígbà tí Ọmọwé Ismail Adéwusì gbà’ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Bákan náà, ó bu’wọ́ lu ìyanni […]

Categories
Ìròyìn

Ẹgbẹ́ A Já Fún Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ènìyàn Pariwo Tantan Síta, Wọ́n Ní Àwọn Kò Sí Lára Àwọn Tó Fẹ́ Yọ Emir Ìlú Kano

YBTC Yorùbá-Ìpéjọ Àpapọ̀ Ẹgbẹ́ ọmọ a já fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Kano ti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú pípè fún ìyọ́ni kúrò nípò Emir ìlú Kano, ìyẹn Muhammad Sanusi II Nínú lẹ́tà tí àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà fi ránṣẹ́ sí Gómìnà Kano, Abdullahi Ganduje, wọ́n ní àwọn kò sí nínú ẹgbẹ́ a já […]

Categories
Ìròyìn

Ipa Tí Àwọn Obìnrin Ńkó Lágbo Òṣèlú Ju Ti Àwọn Ọkùnrin Lọ Igbá-kejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì

YBTC Yorùbá -Igbá-kejì Gómìnà ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, Olóyè Bísí Ẹgbẹ́yẹmí sọ fún àwọn oníròyìn lánàá wípé ipa tí àwọn obìnrin ń kó lágbo òṣèlú ju ti àwọn ọkùnrin lọ, ìyẹn bí a bá wo bí nǹkan ṣe rí lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí. Olóyè Ẹgbẹ́yẹmí wá mu dá àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ ọ̀ún lójú wípé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì […]

Categories
Ìròyìn

Hílàhílo Rọ́lu Ìpínlẹ̀ Kaduna Bí Àwọn Ọmọdé Mẹ́ta Ṣe Di Gbígbésin Láàyẹ̀

YBTC Yorùbá -Hílàhílo rọ́lu àwọn ará àdúgbò Rigasa ní Ìpínlè Kaduna ní òní Ọjọ́bọ bí àwọn ọmọdé mẹ́ta ṣe di gbígbésin láàyè. Ìròyìn fi ìdí rẹẹ̀ lélẹ̀ wípé iyẹ̀pẹ̀ ni ó dà lé wọn lórí ni wọ́n bá gbé ẹ̀mí míì. Olórí Ìmáàmù Mọṣáláṣí Jímọ̀ ti Kalshen Kwalta, Malam Jamilu fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún […]

Categories
Ìròyìn

Ọwọ́ Tẹ̀ẹ́! Ọwọ́ Tẹ Afurasí Tí Ó Ṣe Ikú Pa Òṣìṣẹ́ Àjọ NDLEA Méjì

YBTC Yorùbá – Àjọ tí ón rí sí fífi ọwọ́ ṣù kún òfin mú àwọn tí wọ́n ń gbé egbògi olóró ìyẹn cocain nílè Nàìjíríà ti fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú arákùnrin kan tí ó ṣe ikú pa òṣìṣẹ́ méjì àjọ náà ní oṣù kejì ọdún yìí. Ọ̀daràn náà tí a mọ̀ sí Ohimai Ayodele […]

Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbé’bọnrìn Jí Alábiamọ Méjì Gbèé, Ọmọdé Mẹ́ta, Ṣe Ọlọ́pàá Mẹ́rin Léṣe Ní Ìpínlẹ̀ Adamawa

YBTC Yorùbá – Ìròyìn fìdí rẹẹ̀ múlẹ̀ bíi kẹ̀lẹ̀bẹ̀ wèrè wípé àwọn agbé’bọnrìn kọlu àdúgbò kàn-án tí wọ́n ń pè ní Ganya ní ìjọba ìbílẹ̀ Ganya ní Ìpínlẹ̀ Adamawa lánàá. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù àná ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn agbé’bọnrìn ya wọ àdúgbò náà tí wọ́n sì jì í alábiamo méjì gbèé, wọ́n jí ọmọdé mẹ́ta nílé […]

Categories
Ìròyìn

Ènìyàn Mẹ́ta Ṣòfò Ẹ̀mí Nígbà Tí Ẹnìkan Farapa Yánayàna Nínú Jàm̀bá Ọkọ́ Ní Ojú na Márosẹ̀ Èkó Ṣí Abẹ́òkúta

YBTC Yorùbá -Àwọn Àjọ Ẹ̀ṣọ́ Ojú Pópó ìyẹn FRSC ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ògùn ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lónìí ọjọ́ etí wípé ènìyàn mẹ́ta ni ó jẹ́ ìpè Ọlọ́run ní ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ẹnìkan sì farapa yánayàna nínu jàm̀bá ọkọ̀ tí ó wáyé ní ojúnà Èkó sí Abẹ́òkúta. Ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé láàárín awakọ̀ alùpùpù ìyẹn […]