Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Lórí Owó Òṣìṣẹ́ Tó Kéré Jùlọ: Àjọ Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lápapọ̀ Yóò Dásí Ìkùnsínú Tówà Láàrin Wike àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ní Ìpínlẹ̀ Rivers

YBTC Yorùbá- Òye tí ń fojú hàn báyìí wípé ìkùnsínú tó wà láàárín ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers àti àjọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìyẹn Nigerian Labour Congress (NLC) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Rivers yóò wà sí òpin láìpẹ́ bí àwọn olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń gbìyànjú báyìí láti dá sí ááwọ̀ náà. Ṣáájú àsìkò yìí ni àjọ […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìdí Rèé Tí Mofi Yọ Ẹni Tí ó Jẹ́rí Takòmí Lórí Bí Ilé Aṣòfin Àgbà Ṣe Fẹ́ Yọmí Nípò Ààrẹ – Donald Trump

YBTC Yorùbá- Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn Ààrẹ Donald Trump ti ṣàlàyé lọ́jọ́ àbàmẹ́ta ìdí tí ó fi jáwe gbélé ẹ lé olórí jagunjagun kan tí ó jẹ́ ẹ̀rí takò ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin nígbà ìjíròrò lóri bóyá kí wọ́n yọ́ nípò tàbí kí wọ́n má yọ̀ọ́. Ní ọjọ́ ẹtì ni wọ́n sin Ọ̀gágun Alexander Vindman […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Kòkún Ojú Ọ̀ṣùwọ̀n Tóò Bí Àjọ Elétò Ìdìbò Ilẹ̀ Yìí Ṣe Yọ Orúkọ Ẹgbẹ́ Òṣèlú Mẹ́fà-dín-lọ́gọ́rin Kúrò Nínú Ìwé Ìforúkọsílẹ̀ – Falana

YBTC Yorùbá- Ògbóntàrigì agbẹjọ́rò ní orílẹ̀ èdè yìí tí ó tún jẹ́ gbajúgbajà ajàfún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, Ọ̀gbẹ́ni Fẹ́mi Falana ti bu ẹnu àtẹ lu bí Àjọ Elétò Ìdìbò ní orílẹ̀ èdè yìí ṣe yọ orúkọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kan kúrò nínú ìwé Ìforúkọsílẹ̀ Ẹgbẹ́ Òṣèlú ní orílẹ̀ èdè yìí. Falana ní lóòótọ́ ni òfin […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú Ṣòfin Ilẹ̀ Nàìjíríà Kọ Àbá Kíkó Ọmọ Nàìjíríà Kúrò Ní Orílẹ̀ Èdè China Nítorí Àrùn Coronavirus

YBTC Yorùbá- Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣòfin ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ti kọ ìpè tí àwọn kan ń pè wípé kí ìjọba ilẹ̀ yìí kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní orílẹ̀ èdè China nítorí àrùn Coronavirus tí ó gbalẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè ọ̀ún. Alága fún ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti ìkéde, […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìjọba Ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà Tọwọ́bọ̀wẹ́ Àdéhùn Láti Dá Owó Tí Abacha Kó Pamọ́ Sí Orílẹ̀ Èdè Amerika Padà Sí Orílẹ̀ Èdè Yìí

YBTC Yorùbá-Ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀ èdè yìí àti ti ìjọba ilẹ̀ Amerika ti jọ tọwọ́bọ̀wẹ́ àdéhùn báyìí wípé ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà yóò dá owó tí ó lé díẹ̀ ní Mílíọ̀nù lọ́nà Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta owó ilẹ̀ òkèèrè padà fún ilẹ̀ Nàìjíríà, ìyẹn 308 Million Dollars. Eléyìí jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí ilé aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní orílẹ̀ èdè […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àjọ Ọlọ́pàá Fi Ọwọ́ Ṣùkún Òfin Mú Àwọn Márùn-ún Kan Tí Wọ́n Dẹmọ Wípé Àwọn Ní Àrùn Coronavirus

YBTC Yorùbá –Àjọ agbófinró ti olú ìlú wa Abuja ti fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú àwọn márùn-ún kan tí wọ́n dẹmọ wípé àwọn ti sagbako àrùn aṣeni básubàsu tí ó pànìyàn kiri káàkiri àgbáyé. Àwọn Márùn-ún yìí ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wípé wọ́n yawọ ilé ìwòsàn ńlá kan tí ó wà ní Wuse, […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìdí Rèé Tí A Kò Fi Ní Òògùn Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ (Lassa Fever) Ní Orí-Igbá – Àjọ Àwọn Olóògùn Ilẹ̀ Yìí Sọ̀rọ̀

YBTC Yorùbá -Àjọ àwọn tí ó ń ta òògùn ní orílẹ̀ èdè yìí tí a mọ̀ sí Nigerian Pharmacists ti sọ ìdí tí àwọn kò fi ní òògùn ibà Ìrẹ̀lẹ̀ ní orí-igbá, wọn ní èròǹgbà àwọn ni láti má nìí òògùn náà lóri igbá. Wọ́n ní irú òògùn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe òògùn àìsàn ojóojúmọ́ […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ (Lassa Fever) Ti Ṣe’kúpa Aláboyún Kan Ni Ìpínlè Enugu

YBTC Yorùbá- Ìjọba Ìpínlẹ̀ Enugu ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ibà ìrẹ̀lẹ̀ tí gbogbo wa mọ̀ sí Lassa Fever ti gba ẹ̀mí Aláboyún kan ní ilé ìwòsàn ti ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Utuku-Ozalla ní ìpínlẹ̀ Enugu. Nínú ọdún 2020 yìí, Aláboyún yìí ni ó di ẹ̀nìkejì tí ibà […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Jonathan Farahàn Ní Aso Rock, Ó Ṣe Ìpàdé Bòńkẹ́lẹ́ Pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari

YBTC Yorùbá-Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè yìí, Ọmọwé Goodluck Jonathan ni ó ṣà déédéé yọjú sí ilé ńlá ti ìjọba àpapọ̀ tí a mọ̀ sí Aso Rock ní olú ìlú wa Abuja ní ọjọ́ ọjọ́bọ, tí ó sì ṣe ìpàdé ráḿpẹ́ pẹ̀lú Ààrẹ Muhammadu Buhari. Ìròyìn fidi rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ààrẹ àná náà ṣe ìpàdé […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìjọba Àpapọ̀ Ti Ṣàfikún Owó Àjẹmọ́nú Àwọn Àgùnbánirọ̀

YBTC Yoruba—Ọ̀gágun pátápátá tí ó jẹ́ olùdarí Ikọ̀ Àgùnbánirọ̀ ilẹ̀ yìí, ìyẹn Ikọ̀ tí ó ń rí sí àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ wa tí ń ṣiṣẹ́ sin orílẹ̀ èdè yìí lọ́wọ́ báyìí, ìyẹn tí a mọ̀ sí National Youth Service Corps (NYSC), Ọ̀gágun Shuaibu Ibrahim, ti sọ wípé ìjọba àpapọ̀ ti buwọ́lu àfikún owó Àjẹmọ́nú àwọn […]