Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Àádọ́rin Ènìyàn Lu Jàm̀bá Bí Ilé Àyẹ̀wọ̀ Ìlera Fún Àwọn Tí Wọ́n Ní Àrùn Coronavirus Ṣe Dàwó Lulẹ̀ Ní Orílẹ̀ Èdè China

YBTC News Yoruba—Bí àádọ́rin ènìyàn ni ó ti rá sínú pàlàpálá ilé àyẹ̀wọ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa fi àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè China sí ṣe dàwó lulẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àbàmẹ́ta. Bí èèyàn méjìdínlógójì ni àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí ti rí yọ báyìí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ilé […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ẹṣọ́ra Fún Ìròyìn Ẹlẹ́jẹ̀ Lórí Ẹ̀rọ Alátagbà – Mínísítà Fún Ètò Ìlera Ṣe Ìkìlọ̀

YBTC News Yoruba—Lẹ́yìn ìkéde àrùn apànìyàn tí ó gbalẹ̀ kan ní àgbáyé, ìyẹn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Dókítà Osagie Ehanire ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà níbi mímagbé Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ kiri lóri ẹ̀rọ alátagbà, ìyẹn social media. Mínísítà náà sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ilé Ẹjọ́ Sọ Olisa Metuh Sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méje

YBTC News Yorùbá-Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn Olisa Metuh ni ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Abuja ti sọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje báyìí lórí ẹ̀sùn ìṣe owó ìlú mákumàku ṣáájú ìdìbò ọdún 2015 ní èyí tí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ fìdí rẹ mi. Adájọ́ […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Kòsí Àní Àní, Ó Di Dandan Kí Àmọ̀tẹ́kùn Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin – Obasa àti Gani Adams Sọ̀rọ̀

YBTC News Yorùbá-Ààrẹ Ọ̀nà Kankafò Fún Gbogbo Yorùbá, Iba Gani Adams àti Agbẹnusọ fún ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Mudashiru Obasa sọ ní ọjọ́ ajé wípé kò sí àní àní, Àmọ̀tẹ́kùn yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò ní ìpínlẹ̀ Èkó àti káàkiri gbogbo iwọ́ oòrùn gúúsù orílẹ̀ èdè yìí. Àwọn méjèèjì sọ̀rọ̀ yìí […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

A Ní Atọ́ka Gbogbo Ẹni Tí ó Ní Àrùn Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ – Ilé Ìwòsàn Ilé Ìwé Gíga Ti Ìpínlẹ̀ Èkó Ìjọba Àpapọ̀

Alága fún ìgbìmọ̀ agbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìlera ní ilé ìwòsàn ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Lagos University Teaching Hospital, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Wasiu Adeyemo ti sọ wípé àwọn ní atọ́ka fún gbogbo àrùn ibà Ìrẹ̀lẹ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí. Ó ní òun lè fọwọ́ sọ yà wípé ilé […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ilé Ẹjọ́ Pàṣẹ Pé Kí Wọ́n Fi Ọwọ́ Ṣù kún Òfin Mú Ọ̀gá Àgbà Aṣọ́bodè Tẹ́lẹ̀ Rí Ní Orílẹ̀ Èdè Yìí

YBTC News Yorùbá- Ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó fìdí kalẹ̀ sí Abuja ti pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fi ọwọ́ ṣù kún òfin mú Ọ̀gá Àgbà tẹ́lẹ̀ rí ní ilé iṣẹ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ yìí, ìyẹn Nigerian Customs Service, Ọ̀gágun Abdullahi Dikko. Adájọ́ Ijeoma Ojukwu pàṣẹ wípé kí wọ́n lọ mú Dikko látàrí […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun Buwọ́lu Ìdásílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

YBTC Yorùbá- Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun ti buwọ́lu ìdásílẹ̀ Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò tí gbogbo àwọn gómìnà ìwọ oòrùn gúúsù panupọ̀ láti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò agbègbè tí amọ̀sí Àmọ̀tẹ́kùn ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣe ìbuwọ́lu rẹ̀ ní ibi ìjókòó àwọn aláṣẹ nílé ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí ó wà ní Òkè Mosàn, ní olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari Ṣe Ìbẹ̀wò Sí Ìlú Maiduguri Lórí Ọgbọ̀n Èèyàn Tí Boko Haram Pa

YBTC Yorùbá- Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú Maiduguri ní ìpínlẹ̀ Bornu láti bá àwọn ará ìpínlẹ̀ náà kẹ́dùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ afẹ̀míṣòfò tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram ṣe ní ìlú náà láìpẹ́ yìí. Níbi ìkọlù tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram náà ṣe, èèyàn ọgbọ̀n ni ó fẹ̀mí ṣòfò. […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Lórí Owó Òṣìṣẹ́ Tó Kéré Jùlọ: Àjọ Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lápapọ̀ Yóò Dásí Ìkùnsínú Tówà Láàrin Wike àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ní Ìpínlẹ̀ Rivers

YBTC Yorùbá- Òye tí ń fojú hàn báyìí wípé ìkùnsínú tó wà láàárín ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers àti àjọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìyẹn Nigerian Labour Congress (NLC) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Rivers yóò wà sí òpin láìpẹ́ bí àwọn olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń gbìyànjú báyìí láti dá sí ááwọ̀ náà. Ṣáájú àsìkò yìí ni àjọ […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ìdí Rèé Tí Mofi Yọ Ẹni Tí ó Jẹ́rí Takòmí Lórí Bí Ilé Aṣòfin Àgbà Ṣe Fẹ́ Yọmí Nípò Ààrẹ – Donald Trump

YBTC Yorùbá- Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn Ààrẹ Donald Trump ti ṣàlàyé lọ́jọ́ àbàmẹ́ta ìdí tí ó fi jáwe gbélé ẹ lé olórí jagunjagun kan tí ó jẹ́ ẹ̀rí takò ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin nígbà ìjíròrò lóri bóyá kí wọ́n yọ́ nípò tàbí kí wọ́n má yọ̀ọ́. Ní ọjọ́ ẹtì ni wọ́n sin Ọ̀gágun Alexander Vindman […]