Categories
Eré Ìdárayà

Ìròyìn Pàjáwìrì: Ikọ̀ West Ham United Ti Jáwèé Gbélé Ẹ Lé Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Wọn Lọ́wọ́

YBTC Yorùbá-Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú West Ham United ti jáwèé gbélé ẹ lé Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Manuel Pellegrini lọ́wọ́ lẹ́yìn tí Ikọ̀ ọ̀ún pàdánù nílé wọn sí ọwọ́ Ikọ̀ Leicester City. Ayò Méjì sí oókan ni Ikọ̀ Leicester City fi bá West Ham United wí lẹ́yìn ìkùlé wọn nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn méjèèjì. Ní kété tí […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Wolve Pa Man City Lẹ́kún Bí Ó Ṣea Dáná Ìyà Fún Wọn Yá

YBTC Yorùbá-Ìgbàgbọ́ Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Manchester City láti dé adé líígì bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wọmi ni ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ ẹtì bí Ikọ̀ Wolve ṣe dáná fún wọn yá. Ayò mẹ́ta sí méjì ni Wolve fi gbẹ̀yẹ lọ́wọ Manchester City nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ tí ó wáyé láàárín àwọn Ikọ̀ méjèèjì. Ipò kẹta ní Manchester City wá báyìí ní […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Arsena Ní Láti Ṣe Àtúnṣe Sí Ìbáṣepọ̀ Tí ó Wà Láàrin Ikọ̀ Náà Àti Àwọn Olólùfẹ́ Wọn – Mikel Arteta

YBTC Yorùbá- Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá tuntun fún ikọ̀ Arsena, Ọ̀gbẹ́ni Mikel Arteta ti ní ó pọn dandan báyìí fún ikọ̀ Arsena láti so okùn ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin Ikọ̀ ọ̀ún àti àwọn olólùfẹ́ wọn. Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá tuntun náà ṣàlàyé wípé bí Ikọ̀ náà bá lè dáná ìyà fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Chelsea, yóò mú àwọ̀ tuntun bá Ikọ̀ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Southampton Wó Stamford Bridge Lu lẹ̀ Pẹ̀lú Ayò Méjì Sí Òdo

YBTC Yorùbá- Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Chelsea tí a mọ̀ sí The Blues pàdánù sí ọwọ́ àlejò wọn nírọ̀lẹ̀ ọjọ́bọ. Southampton tó ń jà fitafita nínú àtẹ líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbẹ̀yẹ lọ́wọ Ikọ̀ Chelsea tí ó gbá ni àlejò.Ayò Méjì sí òdo ni Southampton kó lé ẹni tí ó gbà á lálejò. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Ikọ̀ […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ẹgbẹ̀ Agbábọ́ọ̀lú Ìtàló Gba Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Tuntun Bí Wọ́n Ṣe Yẹ Àga Mọ́ Ẹni Tó Wà Níbẹ̀ Tẹ́lẹ̀ Nídìí

YBTC Yorùbá- Giuseppe Lachini ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá tuntun fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Fiorentina nílẹ̀ Ìtàló bí Ikọ̀ náà ṣe jáwe gbélé ẹ lé Ọ̀gbẹ́ni Vincenzo Montella lọ́wọ́. Lachini jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún-lèé-làdọ́ta. Tí àwọn aláṣẹ ikọ̀ náà rí gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó ká ojú òṣùwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ náà. Wọ́n ní Lachini jẹ́ Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá […]

Categories
Eré Ìdárayà

Alex Iwobi Yóò Wà Ní Ìjókòó Fún Ọ̀sẹ̀ Méjì – Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Carlo Ancelotti

YBTC Yorùbá- Ìròyìn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ọ̀sẹ̀ méjì gbáko ní Alex Iwobi ma fi wà lórí ìjókòó láì gbá bọ́ọ̀lù ní ori pápá. Iwobi jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù jẹun ní ikọ̀ Everton ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá ikọ̀ Everton, Carlo Ancelotti ní ó fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ níbi […]

Categories
Eré Ìdárayà

Àjọ CAF Gbọn Orúkọ Ọmọ Nàìjíríà Yọ Kúrò Nínú Àwọn Tí Yóò Figagbága Fún Àmì-Ẹ̀yẹ Ẹni Tó Mọ Bọ́ọ́lù Gbà Jùlọ Nílẹ̀ Aláwọ̀-dúdú Ní Ọdún 2019

Bada Yusuf YBTC Yorùbá-Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, kò sí orúkọ ọmọ Nàìjíríà kankan nínú àwọn tí yóò figagbága láti gba àmì-ẹ̀yẹ ẹni tí ó mọ bọ́ọ́lù gbá jùlo nílẹ̀ Áfíríkà bí Àjọ tó ń rí sí ètò bọ́ọ́lù nílẹ̀ Áfíríkà ìyẹn CAF ṣe kéde àwọn mẹ́ta kan lópin ọ̀sẹ̀. Àwọn mẹ́ta tí Àjọ CAF kéde náà […]

Categories
Eré Ìdárayà

Ǹkan Ò Ṣẹnure Fún Man. U: Ikọ̀ Watford Gbọn Ewúro Sí Wọn Lójú Lánàá

YBTC Yorùbá — Ǹkan ò ṣẹnure fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lú Machester United ní àná bí Ikọ̀ Watford tó wà ní ìsàlẹ̀ àtẹ líígì Gẹ̀ẹ́sì ṣe gbọn ewúro sí wọn lójú lánàá nínú ìdíje àtẹ líígì Gẹ̀ẹ́sì. Àmì ayọ̀ méjì sí òdo ni Watford fi gbẹ̀yẹ ní ọwọ Machester United.

Categories
Eré Ìdárayà

Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Arsenal Gba Àlejò Ọ̀ràn Lánàá, Mẹ́ta Sí Òdo Ni Ó jẹ Ní Ọwọ Man. City

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Arsenal fìdí rẹmi ní ilé wọn lánàá nígbà tí wọ́n gba ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Machester City ní àlejò nínú ìdíje líígì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àlùbámi ni àlejò Machester City náà fi onílé Arsenal ṣe nígbà tí ó báa lálejò ní pápá ìseré Emirate. Ayò mẹ́ta sí òdo ni Machester City fi ṣe ìyà fún Arsenal […]