Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ẹṣọ́ra Fún Ìròyìn Ẹlẹ́jẹ̀ Lórí Ẹ̀rọ Alátagbà – Mínísítà Fún Ètò Ìlera Ṣe Ìkìlọ̀

YBTC News Yoruba—Lẹ́yìn ìkéde àrùn apànìyàn tí ó gbalẹ̀ kan ní àgbáyé, ìyẹn Coronavirus ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mínísítà fún ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Dókítà Osagie Ehanire ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà níbi mímagbé Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ kiri lóri ẹ̀rọ alátagbà, ìyẹn social media. Mínísítà náà sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń […]

Categories
Ìròyìn

Lórí Ìdájọ́ Ìdìbò Bayelsa: Ilé Ẹjọ́ Ní Kí Afe Babalola àti Olanipekun Lọ San Owó Ìtànnà

YBTC News Yorùbá-Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè yìí ti sọ wípé kí Olóyè Afe Babalola àti Olóyè Wole Olanipekun lọ san àádọ́ta Mílíọ̀nù Owó náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtànnà lórí bí àwọn agbẹjọ́rò àgbà méjèèjì ṣe gbá láti tún ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ náà dá pè. Adájọ́ Amina Augie ní ọjọ́ ọjọ́rú […]

Categories
Eré Ìdárayà

Nítorí Coronavirus, Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Láàrin Ikọ̀ Inter Milan Pẹ̀lú Ludogrets Yóò Wáyé Ní Ìdakẹ́rọ́rọ́

YBTC News Yorùbá-Ikọ̀ Inter Milan ti orílẹ̀ èdè Ìtàló yóò gbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹlu Ikọ̀ Ludogrets ní abẹ́lé nínú ìdíje Ọ̀gá-Ọ̀gá, ìyẹn Europa League látàrí Àtànkákẹ̀ àrùn Coronavirus tí ó ń jà ràìnràín káàkiri àgbáyé. Àrùn náà ti kó àwọn aláṣẹ bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá àti ìjọba orílẹ̀ èdè Ìtàló náà sí hílàhílo, lèyí tí ó sì […]

Categories
Eré Ìdárayà

Nemanja Metic Yóò Fi Ikọ̀ Manchester United Sílẹ̀ Lópin Sáà Igbábọ́ọ́lù Yìí

YBTC News Yorùbá-Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, gbajúgbajà ọmọ ilẹ̀ Serbia tí ó ń gbá bọ́ọ́lù jẹun ní ikọ̀ Manchester United ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò fi Ikọ̀ náà sílẹ̀ lópin sáà igbábọ́ọ́lù yìí nígbà tí àdéhùn rẹ̀ pẹ̀lú Ikọ̀ náà yóò dópin. Metic kò ráyè gbá bọ́ọ́lù dáadáa lábẹ́ Akọ́ni-Mọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester […]

Categories
Eré Ìdárayà

Haaland Ọmọ Ọdún Mọ́kàndílógún Gbá Bọ́ọ́lù Sáwọ̀n Nígbà Ogójì Ní Sáà Igbábọ́ọ́lù Yìí

YBTC News Yoruba—Erling Braut Haaland ti gbá bọ́ọ́lù sáwọ̀n nígbà ogójì báyìí nínú gbogbo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí ó ti kópa nínú sáà igbábọ́ọ́lù tí ó ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí. Ọ̀dọ́mọdé ẹlẹ́sẹ̀ eworo lóri pápá náà tú ṣiṣẹ́ àràmàǹdà nígbà tí Ikọ̀ rẹ̀, ìyẹn Borusia Dortmund gbojú Werder Bremen yánayàna ní ọjọ́ àbàmẹ́ta nínú ìdíje àgbákuta […]

Categories
Ìròyìn

Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ (Lassa Fever) Tuntun Ṣẹ́yọ Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna

YBTC News Yoruba—Komíṣọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kaduna, ìyẹn Dókítà Amina Mohammed-Baloni ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ àbàmẹ́ta wípé ibà ìrẹ̀lẹ̀ tí gbogbo wa mọ̀ sí Lassa Fever tún ti ṣẹ́ yọ ní ìpínlẹ̀ náà. Komíṣọ́nà náà sọ wípé arákùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún ni ó ní àrùn náà, […]

Categories
Ìròyìn

Wọ́n Ní Kí Olúwó Lọ Rọ́kúnlé Fún Oṣù Mẹ́fà Nàá – Ìgbìmọ̀ Lọ́balọ́ba Ìpínlẹ̀ Osun

YBTC News Yoruba—Olúwó ti ìlú Ìwó, Ọba Abdurasheed Akanbi ni àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Osun ti ní kí ó lọ rọ́kúnlé ná fún oṣù mẹ́fà ní ọjọ́ ẹtì. Ẹgbẹ́ náà tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ tuntun tí Ọ̀rẹ̀gún ti ìlú Ìlá sì jẹ́ olórí ìgbìmọ̀ náà. Ìṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà ni láti ṣe ìwádìí awuyewuye […]

Categories
Ìròyìn

Ilé Ẹjọ́ Sọ Olùkọ́ Tẹ́lẹ̀ Rìí Ní Ilé Ìwé Gíga Ti Ìjọba Àpapọ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Èkó Sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mọ́kànlélógún Lórí Ẹ̀sùn Ìfipábánilòpọ̀

YBTC News Yoruba—Ilé ẹjọ́ gíga tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ ọjọ́bọ ti sọ olùkọ́ tẹ́lẹ̀ rí kan ní ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn University of Lagos sí ẹ̀wọ̀n ọdún Mọ́kànlélógún Lórí ẹ̀sùn Ìfipábánilòpọ̀ pẹ̀lú ọmọ ọdún méjìdínlógún. Adájọ́ Josephine Oyefeso, nígbà tí ó ń […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

A Ní Atọ́ka Gbogbo Ẹni Tí ó Ní Àrùn Ibà Ìrẹ̀lẹ̀ – Ilé Ìwòsàn Ilé Ìwé Gíga Ti Ìpínlẹ̀ Èkó Ìjọba Àpapọ̀

Alága fún ìgbìmọ̀ agbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìlera ní ilé ìwòsàn ilé ìwé gíga ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Lagos University Teaching Hospital, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Wasiu Adeyemo ti sọ wípé àwọn ní atọ́ka fún gbogbo àrùn ibà Ìrẹ̀lẹ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí. Ó ní òun lè fọwọ́ sọ yà wípé ilé […]

Categories
Ìròyìn Tó Gbajújọ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari Ṣe Ìbẹ̀wò Sí Ìlú Maiduguri Lórí Ọgbọ̀n Èèyàn Tí Boko Haram Pa

YBTC Yorùbá- Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú Maiduguri ní ìpínlẹ̀ Bornu láti bá àwọn ará ìpínlẹ̀ náà kẹ́dùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ afẹ̀míṣòfò tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram ṣe ní ìlú náà láìpẹ́ yìí. Níbi ìkọlù tí àwọn ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò alákatakítí ẹ̀sìn Boko Haram náà ṣe, èèyàn ọgbọ̀n ni ó fẹ̀mí ṣòfò. […]