Categories
Eré Ìdárayà

Real Madrid Dáná Sun Barcelona Bí Ẹran Iléyá,Ojú Messi Pọ́n

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Spanish Laliga, Real Madrid àti Barcelona jọọ wàákò ní pápá ìṣeré Santiago Bernabeu fun ijakadi tani yóò lékè tábìlì.

Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Real Madrid to díyà jẹ Barcelona nínú ìdíje líìgì ni sáà yìí. Ní báyìí, Madrid ti bọ́ sí òkè téńté tábìlì, Atletico Madrid wà ní ipò Kejì pẹ̀lú ìdíje kan lọ́wọ́.

Ayò méjì kọ̀ǹgbà kọ̀ǹgbà ni Madrid gbá sí àwọ̀n Barcelona ní abala kínní. Karim Benzema àti Toni kroos ló gbá ayò méjì náà wọlé.

Abala Kejì ni Barcelona dá ayò kan padà ṣùgbọ́n aṣọ kò bá Ọmọ́yẹ mọ́. Ìgbà tí ìdíje wọ àádọ́rún ìsẹ́jú ni adarí ìdíje náà fún Casemiro ní Káàdì pupa jáde kúrò ní orí pápá.