Categories
Ìròyìn

Orí Yọ Ọba Èkìtì Kan Bí Àwọn Agbébọn Ṣe Yìbọn Fún-un

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn Agbébọn kan ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ti yìbọn fún ọba alayé kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ọba Elewu ti Ewu Ekiti. Ọba Adétutù Àjàyí nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀.

Ọ̀nà ayetoro-Ewu ni ọba Adétutù ń lọ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje. Eléyìí ṣẹlẹ̀ kò tíì ju ọjọ́ kan lọ tí àwọn agbébọn bákan náà lọ gbé ọ̀gá ilé epo kan sálọ ní Iṣan-Ekiti, ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje bákan náà.

Ìròyìn láti Ewu-ekiti sọ ọ́ di mímọ̀ pé ní òwúrọ̀ òní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ni àwọn jàǹdùkú náà bẹ̀rẹ̀ sí níí ejò ìbọn sí ọkọ́ ayọ́kẹ́lẹ́ ọba náà tí ó ń gbé lọ sí Ayétòrò-Ewu ní agbègbè Ido/Osi.

Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé Ọlọhun dóòlà ọba náà, síbẹ̀síbẹ̀ ó fi ara gba ọgbẹ́ yánnayànna bí wọn ṣe rọ̀jò ìbọn fún-un. Ní báyìí, wọ́n ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ náà.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Sunday Abutu jẹ́rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà, ó ṣàlàyé wípé ó ba àwọn nínú jẹ́ púpọ̀. O wáá ṣe ìlérí wípé gbogbo àwọn òṣìkà náà ni owọ́ sìnkú ọlọ́pàá yóò tẹ̀ láìpẹ́.