Categories
Eré Ìdárayà

Leeds Utd Ká Man City Mọ́lé, Wọ́n Lù Wọ́n Bíi Bààrà

YBTC News YORÙBÁ—  Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Leeds United ti lọ bá Manchester City ní buba wọn, wọ́n lù wọ́n bíi bààrà lórí pápá ìṣeré wọn ní Etihad

Ayò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni agbábọ́ọ̀lù Leeds United Stuart Dallas gbá wọlé Manchester City, pẹ̀lú bí adarí ìdíje náà ṣe lé L.cooper kúrò ní orí pápá nígbà tí ó kù sí kí apá kínní wá sópin.

Ìyànú ńlá ló jẹ́ wípé pẹ̀lú bí wọn ṣe lé Cooper kúrò lórí pápá, àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹwàá tí ó kù ni ó tún fi àgbà han Manchester City nínú ilé wọn.

Ní báyìí, Manchester City sì wà ní òkè téńté tábìlì líìgì Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n tí akẹgbẹ́ wọn, Man. Utd bá fi jáwé olúborí nínú ìdíje wọn méjì tí wọn ní lọ́wọ́, àmì mẹ́jọ péré ni yóò kù láàrin wọn.