Categories
Ìròyìn

Ìjọba Àpapọ̀ Tún Ti Sèètò Àwọn Ọkọ̀ Ojú-irin Tuntun. Ẹ Wo Ìlú Tí Wọ́n Wà

YBTC News YORÙBÁ— Mínísítà tí ó ń rí sí ètò ìrìnà ní orílẹ-èdè Nàíjíríà, Rotimi Amaechi ti kéde ní àná ọjọ́ Àbámẹ́ta wípé ìjọba àpapọ̀ ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe okọ̀ ojú-irin mẹ́ẹ́rin tuntun.

Amaechi sọ èyí nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní Àbújá. Lára àwọn àyè tí wọn yóò ṣe àwọn ọkọ̀ ojú irin náà sí ni, Ibadan sí Kano, Port Harcourt sí Maiduguri, Kano sí Maradi àti Èkó sí Calabar.

Mínísítà náà kò sọ àsìkò náà pàtó tí ìjọba àpapọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà, ṣùgbón ó ní mérèèrin yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́.

Amaechi ní gbogbo àwọn ọ̀nà ọkọ̀ ojú-irin yìí niwon ti gbé fún àwọn ilé iṣẹ́ tí yóò ṣe wọ́n. Ó ní àwọn sì ti gbìyànjú láti wá ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìpèníjà tí ó níí ṣe pẹ̀lú owó.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ń retí owó lati China, owó yìí ni wọn yóò bá sí ọ̀ná bv Ìbàdàn sí Kano, àti dídúró dé àwọn ìbuwọ́ lù kọ̀ọ̀kan fún ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà.