Categories
Eré Ìdárayà

Chelsea Pòkọ Ìyà Fún Crystal Palace, Liverpool Pa Aston Villa Lẹ́kún

YBTC News YORÙBÁ— Egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea kanra mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn, Crystal Palace, wọ́n lù wọ́n bíi bẹ̀ǹbẹ́ nàbíyù pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ẹ́rin sí ẹyọkan.

Ami ayo meji kòǹgbà kòǹgbà ni Pulisic gbá wọlé kí Kurt Zouma àti Kai Havertz tóó gbá ayò kọ̀ọ̀kan wọlé.

Liverpool bákan náà ẹ̀wẹ̀ fi àgbà hàn Aston Villa pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gba ayò to jẹ́ kí wọn jáwé olúborí ní isẹju diẹ́ tí ìdíje náà yóò fi dópin.

Ẹ rántí wípé ní ẹṣẹ̀ ìdíje kínní láàrin àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì, Astin Villa Fi ìyà tẹ́ Liverpool lọ́rùn. Méje tọ̀òótọ ni won gbá wọ àwọ̀n Liverpool.