Categories
Ìròyìn

WAEC Ti Kéde Ọjọ́ Tí Ìdánwò Yóò Bẹ̀rẹ̀. Ẹ Wo Ọjọ́ Náà

YBTC News YORÙBÁ— Àjọ tí ó ń rísí ìdánwò fún àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìhà ìwọ̀-oòrùn adúláwọ̀ WAEC, ti kéde pé ìdánwò yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ títí di ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹẹ̀sán, 2021.

Ẹ rántí wípé adarí àjọ náà, Patrick Areghan tí sọ tẹ́lẹ̀ wípé ó ṣe é ṣe kí ìdánwò WAEC tí ó má a ń wáyé ní MAY/JUNE má wáyé ní oṣù náà mọ́ nítorí ipá tí Covid – 19 kó.

Ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí fún ẹka ìbánisọ̀rọ̀ ní orílẹ-èdè Nàíjíríà, Demianus Ojijeogu sọ wípé àtẹ iṣẹ́ fún ìdánwò náà yóò jáde láìpẹ́.

Àjọ náà ti ṣetán láti fi tó gbogbo ilé ìwé, àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ àti gbogbo ọmọ Nàíjíríà wípé ọjọ́ tí ìdánwò yóò bẹ̀rẹ̀ ni August 16 títí di September 30, 2021.