Categories
Ìròyìn

Ọlọ́pàá Ti Mú Àwọn Méjì Fún Gbígbé Ewúrẹ́ Mẹ́wàá Ní Èkìtì

YBTC News YORÙBÁ—  Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Èkìtì ti fi páńpẹ́ òfin mú àwọn afurasí méjì kan pẹ̀lú bí wọ́n ṣe bá àwọn ewúrẹ́ mẹ́wàá tí wọ́n wá kiri ní àkàtà wọn ní Igbemọ-Ekìtì ní ìjọba ìbílẹ̀ Ireposun/Ifelodun.

Mr Sunday Abutu, agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Adó-Ekiti ṣàlàyé pé àwọn ọdẹ ni wọ́n rí àwọn afurasí pẹlu ewúrẹ́ kí àwọn yóó mú wọn.

Abutu sọ pé àwọn ọdẹ ni Igbemọ-Ekìtì ni wọ́n rí àwọn afurasí méjì náà nínú ọkọ̀ Salon Primera tí wọ́n kó ewúrẹ́ mẹwàá tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ tí wọn gbé.

Nígbà tí àwọn ọdẹ pe ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fún àwọn afurasí náà, kíákíá ni àwọn ọlọ́pàá tí dé sí àyè náà tí wọ́n sì mú wọn wá sí agọ́ ọlọ́pàá wọn.

Nígbà tí wọn ń fi ọ̀rọ̀ wá àwọn afurasí náà lẹ́nu wò, wọ́n jẹ́wọ́ wípé àwọn jí gbogbo ewúrẹ́ náà gbé ní Ise-Ekiti, wọn ó wáá tà á ní Adó-Ekiti tí wọ́n ń gbé.