Categories
Ìròyìn

El-Rufai Sọ Pé Tí Àwọn Ajínigbé Bá Gbé Ọmọ Òun Gan, Òun Ò Ní Sanwó

YBTC News YORÙBÁ— Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam El-Rufai sọ pé òun kò níí san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé kódà tí wọn bá gbé ọmọ bíbí inú òun.

El-Rufai sọ èyí di mímọ̀ nínú ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ lórí rẹ́díò ní òní ọjọ́ Àbámẹ́ta láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìṣèjọba òun kò fi àyè sílẹ̀ fún ìdúnádúrà pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú ajínigbé.

El-Rufai máa ń tẹnu mọ́ ọ ní gbogbo ìgbà wípé gbogbo ìjọba kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kékeré mú àwọn ajínigbé. Kódà ó tún sọ ọ́ ní ọjọ́’bọ̀ wípé àwọn jàǹdùkú wọnyí kò lè láti máa gbé ayé.

Ó ṣàlàyé ní òní wípé òun máa ń kìlọ̀ gidigidi fún àwọn mọ̀lẹ́bí òun láti máa sọ́ra fún àwọn ajínigbé kí wọn má gbé wọn. Nítorì òun kò níí sanwó kankan. Ó sì ní kí àwọn náà mà sanwó fún ẹnikẹ́ni

Ó ní òun kò ṣe àwàdà, bó ṣe rí go nìyẹn. Ó ní kódà gan, tí wọ́n bá gbé ọmọ bíbí inú òun gan-an, òun kò ní owó kankan láti fi sílẹ̀ fún àwọn ajínigbé.