Categories
Ìròyìn

Buhari Yan Oyegun Gẹ́gẹ́ Bí Alága Ìgbìmọ̀ UI

YBTC News YORÙBÁ—  Ààrẹ Buhari ti yan alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC nígbàkan rí, John Oyegun gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ ilé ìwé gíga UI ní Ìbàdàn.

Yàtọ̀ sí ilé ìwé UI, àwọn ilé ìwé gíga mìíràn tí ààrẹ Buhari tún yẹn àwọn ìgbìmọ̀ fún ni Yunifásítì Port Harcourt (UNIPORT), Yunifásítì Èkó (UNILAG).

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (OAU), Ile-Ife, àti Maritime University ni ìpínlẹ̀ Delta náà wà níbẹ̀ . MASUD kazaure, Abubakar Maikarfi àti Emeka Nwagbo wà nínú àwọn tí wọ́n yàn sí ara ìgbìmọ̀ UI.

Ní UNILAG, alága ìgbìmọ̀ wọn ni olóyè ọ̀mọ̀wé Lanre Tejuosho. Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tí ó kù ni Ọ̀mọ̀wé Aminu Ahmed, Ọ̀mọ̀wé Uro Gardner, Olóyè Chinedu Adindi àti Mustafa Salihu.

Gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ni Mínísítà ètò ẹ̀kọ́, Adamu Adamu yóò búra fún ní Abuja ní April 19.