Categories
Ìròyìn

Àmọ̀tẹ́kùn Àti Miyetti Allah Ṣe Ìpàdé Ní Ọ̀sun. Ẹ Wo Àbájáde Ìpàdé

YBTC News YORÙBÁ— Ẹ̀ṣọ́ àbò ilẹ̀ Yorùbá, Àmọ̀tẹ́kùn ti ẹka ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ìròyìn ti gbé e wípé wọ́n jọ ń ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Miyetti Allah fún bí ètò ọrọ̀ àbò ìpínlẹ̀ náà yóò ṣe dára.

Àwọn àkójọpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá kan tí wọn pè ní “Kiriji Heritage” to fi ẹ̀hónú ọkàn wọn lánàá pẹ̀lú bí àwọn Fúlàní darandaran ṣe ń wọ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lọ́pọ̀lọpọ̀.

Agbẹnusọ fún , ẹgbẹ náà, Adémọ́lá Ẹkúndayọ̀ ṣàlàyé wípé ó seni laanu pé àwọn Fúlàní darandaran láti ìpínlẹ̀ Kwara ń wọ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun pẹ̀lú bí wọn ṣe ń gba ọ̀nà ìjọba ìbílẹ̀ Odò-Ọ̀tìn wọlé.

Àwọn Fúlàní darandaran yìí ni wọ́n ti lé kúrò ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ó yi ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ká, wn sì ń wọlé olú ọpọlọpọ̀ awọn mààlú wọn, léyí tí yóò dá wàhálà sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun fún àbò wọn.

Ó ní ní ọ̀ṣẹ̀ óò kọjá ní en rí àwọn àjòjì Fúlàní darandaran náà ni agbègbè Owode-Ẹdẹ. Ó ní àwọn Fúlàní náà ló gbé ènìyàn ní Oṣú. Ó sì rọ ìjọba láti gbé ìgbésẹ tí ó yẹ kí ó tóó pẹ́ jù.