Categories
Ìròyìn

JAMB Ti Dá Ètò Ìforúkọsílẹ Dúró

YBTC News YORÙBÁ— Àjọ tí ó ń rísí ètò ìgbaniwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ilé ìwé ńlá ti dá ètò ìforúkọsílẹ̀ sí ilé ìwé ńlá tí ó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ lóní dúró.

Oùdarí ẹka tó ń ṣe ilana ẹgbẹ́ náà, Ọ̀mọ̀wé Fabian Benjamin ní Abùjá, ó ṣàlàyé wípé ìgbésẹ náà wáyé láti lè jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀tọ́ sí àtẹ ayárabíàsá àjọ náà kí ìforúkọsílẹ tóó bẹ ní pẹrẹu.

Àwọn tó ń ṣe ètò ìdánwò sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n máa tẹlé àjọ náà níbi gbogbo ètò wọn láti mọ èyí tí ó kan àti ọjọ́ tí Ìforúkọsílẹ yóò padà jẹ́.