Categories
Ìròyìn

Fúlàní Darandaran 50 Ni NSCDC Ti Mú Ní Òǹdó Àti Àwọn Ìpínlẹ̀ Meji

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí ó ń dáàbò bo àwọn ará ìlú (NSCDC) ti mú àádọ́ta àwọn Fúlàní darandaran pẹ̀lú àwọn èlò ìjà olóró lọ́wọ́.

Ọ̀gá pátápátá àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Ahmed Audi nígbà tí ó ń ṣe ní ṣàlàyé wípé iṣẹ́ ọwọ́ gbogbo àwọn àádọ́ta yìí ni jíjí mààlú kó àti jíji àwọn ènìyàn gbé.

àwọn àádọta afurasí yìí ni wón mú ní Ekiti, Borno, Cross River àti àwọn àgbègbè mìíràn Jákèjádò Nàíjíríà.

Audi ṣàlàyé wípé èròńgbà òun gẹ́gẹ́ bí ọgá tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn ni láti mú àwọn oníṣẹ́ ibi wọnyii àti láti mú ìrẹ́pọ̀ wá láàrín àwọn àgbẹ̀ àti fúlàní darandaran.

Ó lu gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ní ọ̀gọ ẹnu láti dìde gírí sí ètò ààbò àti sísọ́ ẹ̀mí àwọn ènìyàn.