Categories
Ìròyìn

Ẹ Wo Arákùnrin Tó Dáná Sun Olólùfẹ́ Rẹ̀ Rí Àti Ọmọ Rẹ̀ Méjì Ní Ìbàdàn

YBTC News YORÙBÁ—  Arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ahmed Saka ti dáná sun olólùfẹ́ rẹ̀ rí, Mutiat Oladele àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì pa ilé ní ìlú Ìbàdàn.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà ṣẹlẹ̀ ní alaye Ọjọ́’rú ní Shogoye, agbègbè Ìdí-Arẹrẹ, ìlú Ìbàdàn. Ìròyìn jẹ́ kí a mọ̀ wípé Saka àti Mutiat jọ ń fara wọn tẹ́lẹ̀ kí Mutiat yóó kọjúrẹ̀ sí oòrùn alẹ́.

Saka ti ń halẹ̀ mẹ̀ọ́ Mutiat to wípé òun yóò pa á ati ara òun tí Mutiat bá kọ̀ jálẹ̀ wípé òun kò fẹ́ òun mọ́. Ó sì padà mú ìlérí rẹ ṣẹ olú bí ó ṣe dáná sun Mutiat ní òru.

Lẹ́yìn ìgbà tí ó dáná sun Mutiat ati awọn ọmọ méjì pa ilé, Saka náà padà kú. Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Olúgbénga Fádèyí fìdí ọrọ̀ náà múlẹ̀ wípé lóòótọ́ ni ìṣẹlẹ náà.