Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbébọn Tún Ti Gbé Òṣìṣẹ́ Kùsà Mẹ́ta Ní Ìbàdàn

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn agbébọn kan tí a fura sí gẹ́gẹ́ bí gbọ́mọgbọ́mọ ti ṣe ìkọlù sí àyè ìwakùsà kan ní ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Wọ́n kó ènìyàn mẹ́ta lọ.

Orúkọ àyé ìwakùsà yìí ni Megabolex Quarry, ní ìdí Ayunre, ní ọ̀nà Ibadan-Ìjẹ̀bú Òde ní ìjọba ìbílẹ̀ Oluyole. Ní déédé aago mẹ́rin-àbọ̀ ọ̀sán ni wọ́n gbé wọn.

Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ Kùsà náà tí orí kó yọ lọ́wọ́ àwọn Ajínigbé, Tope Solomon ṣàlàyé wípé ní déédé aago máárùn-ún ìrọ̀lẹ́ ni wọn gbé àwọn òṣìṣẹ́ mẹrin náà lọ.

Solomon sọ wípé àwọn tí àwọn agbébọn náà gbé lọ ní Ubong Jacob, Amisu Isaac àti Wasiu. Ó ṣàlàyé wípé àwọn kò mọ ibi tí wọn kó wọn lọ pàtó.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Olúgbénga Fádèyí náà sọ wípé lóòótọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ṣàlàyé wípé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá olú iranlọwọ àwọn ọdẹ ti ń ṣe ìgbìyànjú láti rí àwọn mẹtẹ̀ẹ̀ta.