Categories
Ìròyìn

Tinúbú Ní Àwọn Ọ̀tá Tó Pọ̀ Gan Nínú APC – Onu

YBTC News YORÙBÁ— Àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ọmọọba Onu ti sàlàyé wípé àwọn ọ̀tá Gómìnà Èkó tẹle rí, Asíwájú Bọ́lá Ahmed Tinúbú nínú ẹgbẹ́ APC ló ń ṣiṣẹ́ takòó.

Onu sọ wípé àwọn ọ̀tá Tinúbú ọ̀ún ló ń gbé gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ wípé Tinúbú ati ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ń bá ara wọn jà kiri.

Ó tẹ̀ síwájú wípé ọ̀rẹ́ tímọ́tīmọ́ ni Buhari àti Tinúbú. Pàápàá jùlọ wọ́n dìnọ dá egbẹ́ tó ń ṣe ìjọba APC silẹ̀ ni ní síwájú ìbò ọdún 2015.

Ó ní ọgbọn àti ọpọlọ ìṣèjọba Tinúbú ló jẹ kí ó ní àwọn ọmọlẹ́yìn jákèjádò Nàìjíríà. Èyí ló ń bí àwọn ọ̀tá rẹ nínú pẹlu àhesọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbé kiri.