YBTC News YORÙBÁ— Olùkọ́ kan ní ẹka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ayé ilé ìwé ńlá Adekunle Ajasin, ìlú Àkùngbá Àkókó, ní ìpínlè Òǹdó Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlátúndé Adégbuyi ni ó ti ìròyìn sọ pé ó kú sí inú ọkọ̀ rẹ̀.
Ohun tí ó ṣe okùnfà ikú rẹ̀ kò yé wá títí di àsìkò yìí. Ọ̀kan nínú àwọn alábágbé rẹ̀ ló ṣe àkíyèsí òkú rẹ̀ nínú ọkọ rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ títì Akungba.
Ìròyìn fi yé wa wípé olóògbé náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀yìn tì lẹnu iṣẹ́ ni, ṣùgbón ó sì ní ajọṣepọ pẹlu ilé ìwé náà. A gbọ́ wípé àlàáfíà ló wà ní gbogbo òwúrọ̀ Ọjọ́ rú kí ó tóó kú.
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Tee-Leo Ikoro sọ wípé lóòtọ̀ ni ọ̀rọ̀ náà. Ó ní àwọn tí ń ṣe ìwádìí ohun tí ó fa ikú olùkọ́ náà.
Ó ṣàlàyé wípé nígbà tí àwọn dé ibi òkú náà, kò sí àpẹẹrẹ wípé ẹnikẹ́ni fi ọwọ́ kàn-án. Ó ní ọmọ àádọ́rin ọdún ni olóògbé náà.