Categories
Ìròyìn

Ìjọ Kérúbù Àti Séráfù Ti Ilé Ìjọsìn Mẹ́ẹ́rin Pa. Ẹ Wo Ohun Tí Wọ́n Ṣe

YBTC News YORÙBÁ— Ilé ìjọsìn Kérúbù Àti Séráfù ti sọ àgádágodo sí àwọn ẹka ilé ìjọsìn wọn mẹ́rin kan ní Àkúrẹ́ fún àwọn ìhùwàsí àìtọ́.

Àwọn ilé ìjọsìn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n tì pa yìí ni wọ́n sô wípé wọn kópa nínú àwọn òògùn dúdú, ẹbọ ṣíṣe, èyí tí ó lòdì sí ìlànà ìjọ tí kò sì bá òfin ọmọlẹyìn kristi gidi mu.

Ààrẹ ìsọkan ìjọ Kérúbù àti Séráfù ní Òndó, Primate Ade Ademisokun ṣàlàyé pé àwọn tí àwọn ilé ìjọsìn náà pa nítorí wípé wọn kò mọ ìlànà ìlé ìjọsìn C&S, wọ́n kàn án ṣe ti ara wọn ní.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ká ǹkan dúdú, ǹkan awo mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìjọ àwọn kò sì gba eléyìí láàyè. Ó ní àwọn tó ṣetán láti kọ́ ẹ̀kọ́ yóò gba ìdánilẹ́kọ́ tí ó péye, àwọn á sì fi wọ́n ṣí abẹ́ àmójútó.

Ó ṣàlàyé wípé ìgbésẹ̀ yìí ni láti mú ìsọ̀kan wá láárín ìjọ náà, àti láti jẹ́ kí ẹ̀sìn wà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yẹ.