Categories
Ìròyìn

Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re Wípé Àwọn Ò Sọ Pé Àwọn Gbé Tinúbú Lọ́wọ́ Fún Ààrẹ 2023

YBTC News YORÙBÁ— Ẹgbẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá àtàtà, Afẹ́nifẹ́re ti fohùn ráńṣẹ́ sí gbogbo ọmọ Nàíjíríà wípé àwọn kọ́ ni àwọn sọ pé àwọn ti fi ẹnu kò mú Tinúbú gẹ̀gẹ́ bí ààrẹ wọn ọdún 2023.

Ẹ rántí wípé adarí àwọn ìdàgbàsókè ọmọ ilẹ́ Yorùbá kan, Ọmọọba Dayo Adéyẹyè sọ wípé àwọn ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ti fi ẹnu kò wípé Bọla Ahmed Tinúbú ní àwọn mú gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àwọn ní 2023.

Ní báyìí, adarí ẹka ìbánisọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ náà, Ṣọlá Lawal ní òní Ọjọ́’rú ti ya ọ̀rọ̀ náà balẹ̀. Wọ́n ní àwọn kò gbé ẹnikẹ́ni ldání gẹ́gẹ̀ bí ààyò àwọn sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2023

Lawal ṣàlàyé wípé àwọn ṣì ń ṣe ọ̀fọ̀ Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Yínká Odùmákin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di olóògbé. Ní báyìí, àwọn ti fagi le gbogbo eto fún ìrántí olóògbé.

Dájúdájú ọ̀rọ̀ burúkú tí kò ní ìtumọ̀ ní Adéyẹyè ń fi ẹnu rẹ̀ sọ nígbà tí ó lọ kí ààrẹ Afẹ́nifẹ́re tí o gbéṣẹ̀, Reuben Fasoranti. Ó ní bàbá ti kúrò ní ààrẹ, kí ó jẹ kí bàbá ó sinmi nílé.