Categories
Ìròyìn

Àwọn Ọmọ Ológun Ti Fi Bọ́m̀bù Da Àyè Ìṣápamọ Àwọn Agbébọn Imo Rú

YBTC News YORÙBÁ— Ìbẹ̀rùbojo bo gbogbo àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ Essien Udim ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun pẹ̀lú bí àwọn ọmọ ológun ṣe fi bọ́ḿbù tú gbogbo inú igbó Ikot Akpan.

Èròńgbà àwọn ọmọ ológun ni láti túká àti láti da àyè àkójọpọ̀ àwọn ọ̀daràn náà rú. Pàápàá pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń fi ojoojúmọ́ se ìkọlù sí àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Imo.

Àwọn ará àdúgbò tí wọ́n dìjọ pààlà àti àwọn ọ̀daràn náà ní ìró bọ́ḿbù náà bẹ̀rẹ̀ sí níí fún lákọ láti aago mẹ́jọ alaye Títí di aago méjìlá òru àná.

Ìgbéṣẹ̀ àwọn ọmọ ológun yìí wáyé ni bíi wákàtí mẹ́rìnlélógún lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà dáná sun ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ńlá tí ó wà ní Imo àti ọgbà àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà ní Owerri.

Ààrẹ Muhammadu Buhari láti ẹnu abẹ́sinkáwọ́ rẹ̀ àgbà fún ìkéde, Garba Sheu ní ọjọ́ Ajè ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun ẹ̀sọ́ aláàbò kí wọn lọọ dáná sun gbogbo àwọn tó ń ṣe ìkọlù náà.