Categories
Ìròyìn

Ẹ Wo Ohun Tí Makinde Ṣèlérí Wípé Òhun Á Fún Àwọn Tí Iná Jó Dúkìá Wọn Ní Ìbàdàn

YBTC News YORÙBÁ— Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú àti ọ̀tọ̀ǹkùlú àwọn oníṣòwò ẹ̀yà ara ọkọ̀ tí iná sé ìjànbá fún ni Agidi Gate nílú Ìbàdàn.

Ìpàdé náà ni láti dín òfò àti ǹkan tí ó nù wọ́n kù àti láti fún àwọn tó fara gbá nínú ìjànbá náà ní owó. Ìpàdé ọ̀ún wáyé ní ilé ìjọba ni Agódi Ìbàdàn.

Nígbà tí gómìnà ń bá àwọn aṣojú náà sọ̀rọ̀, ó sọ wípé ìdí pàtàkì tí òun fi pè wọ́n ní látí jíròrò àwọn ohun ẹ̀bùn tí yóò tètè tu àwọn tí ó pàdánù dúkìá wọn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta lójú.

Bákan náà ló sọ wípé ìpàdé náà yóò tún wá àbáyọ sí ọjà náà fún dídènà ìjànbá ọjọ́ iwájú. Ó sì kẹ́dùn olú wọn wipe kí wọn mọ̀ dájú wípé kò sí ohun tí àwọn fi fún wọn tí yóò dà bí ohun tí ó Jóná.

Lẹ́yin ìpàdé, Bàbálọ́jà ọjà náà, Waheed Azeez dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gómìnà. Ó sọ pé Gómìnà ṣe ìlérí wípé òun kò níí lé àwọn kúrò ní ààyè náà, ó sì sọ wípé òun yóò tún ọjà náà kọ́ dáadáa ní ti ìgbàlódé.