Categories
Ìròyìn

Àwọn Fúlàní Darandaran Ṣá Àwọn Agbẹ̀ Ṣákaṣàka Ní Ìrele-Ekiti!

YBTC News YORÙBÁ— Kò tíì tó oṣù kan tí àwọn Fúlàní darandaran pa àwọn àgbẹ̀ méjì kan jáujàku ní Isaba-Ekiti. Wọ́n tún ti ṣe àwọn àgbẹ̀ mẹ́ta mìíràn bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojúní Irele- Èkìtì.

Nínú ìjọba ìbílẹ̀ kan náà ni àwọn ìlú méjèèjì yí wà. Àwọn Fúlàní ọ̀ún jẹ́ méfà, tí wọn sì kó àwọn ohun èlò ìjà lọ́wọ́ kítikìti kí wọn tó ṣe ìkọlù sí àwọn àgbẹ̀ mẹ́ta náà nínú ọkọ.

Ìròyìn jẹ́ kí á mọ̀ wípé ọgbẹ́ tí wọn dá sí àwọn àgbẹ̀ náà lára kò kéré rárá. Apá kan ayé àti ọ̀run ni wọ́n wà. Ilé ìwòsàn ńlá Ikole ni wọ́n sáré kó àwọn àgbẹ̀ náà lọ dìgbàdìgbà.

Wọ́n bèèrè owó lọ́wọ́ àwọn obìnrin meta náà, ṣùgbón wọn kò ní ju N200 lọ. Lẹ́yìn tí wọn gbà owó ọ̀ún tán ni wọ́n fẹ́ bá wọn sùn. Kíkọ̀ jálẹ̀ wọn lo jẹ́ kí wọn sáwọn, Ọlóhun nikan ló lè dóòlà wọn.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, ASP Sunday Abutu sàlàyé wípé lóòótọ ni ìkọlù sí àwọn obìnrin mẹ́ta náà ní òwúrọ̀ yìí. Ìwádìí sì ti ń lọ lọ́wọ́ láti fi ojú àwọn òṣìkà, aṣebi ẹ̀dá ọ̀ún hàn.