Categories
Ìròyìn

Àwọn Agbébọn Tún Dáná Sun Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá Mìíràn Ní Imo

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn Agbébọn ní òní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tún ti dáná sun olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mìíràn tí ó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ehime Mbano ní ìpínlẹ̀ Imo.

Kò tíì ju ọjọ́ kan péré lọ, nì àná tí àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ẹ̀dá kan dáná sun ilé iṣẹ ọlọ́pàá tí wọn ń kó àwọn ẹlẹwọn sí, tí wọn sì tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n 1,884 sílẹ̀.

Kò tíì pé ọjọ́ kan tí igbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí, Yẹmí Òsíbàǹjo, ọgá ọlọ́pàá tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lenu iṣẹ́ ati àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lọ sí ini iṣẹlẹ náà, bú ẹnu àtẹ́ lu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀, ti òmíràn tún fi ṣẹlẹ̀.

Ìròyìn jẹ́ kí á mọ̀ wípé lenu oṣù Kejì sí oṣù kẹta ọdún yìí, wọn ti dáná sun àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bíi mẹ́rin, wọn ti pa ọlọ́pàá mẹta, tí wọn sì ṣe ọpọlọpọ olópàá léṣe.