Categories
Ìròyìn

Àtíkù Kò Lè Díje Fún Ipò Ààrẹ, Kìí Ṣe Ọmọ Nàíjíríà – Malami

YBTC News YORÙBÁ—  Agbẹjọ́rò gbogbo-gbòò fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abubakar Malami ti sọ fún ilé ẹjọ́ ńlá tí ó kalẹ̀ sí Abùjá wípé igbákejì ààrẹ ní ìgbà kan rí, Àtíkù Abubakar kò lee díje sí ipò ààrẹ.

Ẹ ó rántí wípé ní ọdún 2019, àjọ kan tí orúkọ rẹ̀ń jẹ́ EMA gbé Àtíkù lọ sí ilé ẹjọ́ wípé kò lẹ́tọ́ láti díje sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí àbínibí rẹ̀.

Malami bákan náà, òun olú àwọn amòfin ẹgbẹ́ rẹ̀ tó kù ti Oladipo Okpeseyi ṣáájú fúnní ilé ẹjọ́ dìjọ sàlàyé wípé Atiku kìí ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Malami ṣe àlàyé lẹ́kúnrẹ́rẹ́ wípé ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1946 ni wọn bí Atiku sí Jada, ní orílẹ̀-èdè Àríwá Cameroon. Ní ọdún 1961 ni ìlú Jada tó ó dara papọ̀ mọ́ Nàìjíríà.

Àkójọpọ̀ ọdún 1961 ni ó kó Jada papọ̀ mọ́ Nàìjíríà. Kìí ṣe ọmọ bíbí Nàìjíríà olú bíbí ni, bí kò ṣe olú àkójọpọ̀. Bàbá rẹ̀ gan ti kú kí àkójọpọ̀ tóó tó ní ọdún 1961.