Categories
Ìròyìn

Àjọ ASUP Ti Gùn Lé Ìyanṣẹ́ Lódì

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Polí, ASUPti gùn lé ìyanṣẹ́ lódì tí kò ní gbèdéke ọjọ́ tí wọn yóò wọlé padà nítorí àìfún àwọn òṣìṣẹ́ ní owó gidi.

Ààrẹ àjọ náà, Anderson Ezeibe kéde èyí ní òwúrọ̀ òní ọjọ́ Ìṣẹgun ní Abuja. Ó ṣàlàyé pé gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ASUP náà ló tí jọ́ ọ fẹnu kò láti ti àwọn ilé ìwé pa títí tí ìjọba yóò fi dáwọn lóhùn.

Ẹ rántí wípé ìjọba àpapọ̀ ti pe gbogbo àwọn adarí àjọ náà sí ìpàdé pàjáwìrì ní ọjọ́ Ajé láti má jẹ́ kí wọn lọ fún ìyanṣẹ́ lódì náà.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ìpàdé pàjáwìrì ìjọba àpapọ̀ náà, pàbó ló já sí, ASUP ti gùn lé ìyanṣẹ́ lódì àìlọ́jọ́ ka pàtó ní òní pẹ̀lú bí ìjọba kò ṣe mú àdéhùn wọn ṣẹ.