Categories
Eré Ìdárayà

Manchester United Pòkọ Ìyà Fún Brighton, Newcastle Ba Ayọ̀Tottenham Jẹ́

YBTC News YORÙBÁ— Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United ní alaye yìí wá láti ẹ̀yìn fi ìyà jẹ Brighton & Hove Albion. Ayò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbá sínú àwọ̀n wọn.

Bákan náà ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Tottenham, èyí tí olùkọ́ni Jose Mourinho kó sòdí rí ìjákulẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Nígbà tí wọn sọ ìdíje náà di ọ̀mì ọ̀mì nígbà tí ó kù díẹ̀ kí ó wá sí òpin

Atamátáṣé ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United nígbà kan rí, Danny welbeck ló kọ́kọ́ fi orí kan ayò kan wọ ilé Manchester United kí wọn tó ó fi gba méjì padà ní ìpín Kejì ìdíje náà.

Ni báyìí Manchester United sì wà ní ipò Kejì ní orí tábìlì líìgì Gẹ̀ẹ́sì tí Manchester City sì wà lókè téńté.