Categories
Ìròyìn

Ìjọba Àpapọ̀ Ti Sún Isopọ̀ NIN-SIM Síwájú Pẹ̀lú Oṣù Kan

YBTC News YORÙBÁ—  Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sún ọjọ́ tí ètò ìsopọ̀ NIN-SIM yóò wá sópin to síwájú pẹ̀lú oṣù kan gbáko.

Agbẹnusọ fún àjọ NIMC jákèjádòló Nàíjíríà Káyọ̀dé Adégòkè ló sọ èyí mímọ̀ ní olú ìlú Abùjá ní àná ọjọ́ Ẹtì ní.

Ìsún síwájú yìí ni wọ́n sún láti April 6, 2021 tí ó yẹ kó wá sópin tẹ́lè títí di May 6, 2021 lẹ́yìn ìgbà tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà gbà láti tèsíwájú níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́’rú.

Mínísítà fún ètò ìbánisọ̀rọ̀ àti ọrọ̀ ajé Isa Pantami ló darí ìpàdé náà. Ó sì gbé àbájáde ìpàdé lọ sí iwájú ààrẹ, ó sì buwọ́ lú u.

Ẹ rántí pé láti ọjọ́ oṣù Kejìlá ọdún tó 2020 ní ìjọba àpapọ̀ ti kọ́kọ́ kéde wípé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìsopọ̀ NIN-SIM rẹ̀ yóò pàdánù kaadi siimu rẹ, lẹ́yìn ìgbà náà ni wọn bẹ̀rẹ̀ síí sun títí di àsìkò yìí.