Categories
Eré Ìdárayà

Chelsea Gba Àlejò Ọ̀ràn, Westbrom Ba Ọmọlúàbì Wọn Jẹ́.

YBTC News YORÙBÁ—  Awọn Yorùbá máa ń pòwe wípé a ò kìí sùn nílé ẹni kí á fi ọrùn rọ́. Òwe yìí kò ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea, wọ́n gbà àlejò ọ̀ràn nì ìrọ̀lẹ́ ònì ní pápá ìṣeré wọn, Stamford Bridge.

Ayò máárù-ùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn akẹgbẹ́ wọn, West Brom Albion, tì ó wá ká wọn mọ́lé, dà sínú àwọ̀n wọn. Ayò méjì méjì ní Matheus Pereira àti Callum Robinson gbá wọ ilé wọn.

Ìṣẹ́jù mọ́kàndìnlọ́gbọ̀n ni adarí ìdíje náà yọ Káàdì aláwọ̀ pupa fún agbá ẹ̀yin fún Chelsea, Thiago Silva, èyí sì mú kì West Brom ki Chelsea bí Ẹkùn miran tì wọn sì nà wọ́n nì máárùn-ùn sí méjì.

Ìyà àlùbami yìí ni ìyà àkọ́kọ́ tì akọ́ni-mọ̀ọ́gbá tuntun tí Chelsea ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà, Tuchel yóò km jẹ nínú líìgì Gẹ̀ẹ́sì.