Categories
Ìròyìn

Agbẹnusọ Fún ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Yinka Odumakin Ti Jáde Láyé

YBTC News YORÙBÁ—  Agbenusọ fún ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ilẹ̀ Yorùbá, Yínká Odùmákin ti papò dà ní ilé ìwòsan ńlá olùkọ́ni tí ó wà ní ìlú Èkó lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Ìyàwó rẹ̀, ìyáàfin  Joe Okei-Odumakin ló sọ èyí di mímọ̀ ní òní ọjọ́ Àbámẹ́ta. Olóògbé Odùmákin ṣe gudugudu méje yàyà méfà fún ìdàgbàsókè Yorùbá.

Pàápàá jùlọ ní ọdún 1993 ní ìgbà tí wọn fagi lé ìbò tí ó gbé Abiola wọlé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìfẹ́ ilẹ̀ Yorùbá wà lóòókán àyà rẹ̀ gan.

Olóògbé Odùmákin tun gbé onílámèyítọ̀ mìíràn ní ìyàwó, Ọ̀mọ̀wé Joe Okei-Odumakin, ẹni tí ó ń ta ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari tí ó wà lóde yìí lẹ́nu gidigidi gan.

Odùmakin máa ń fi ojoojúmọ́ ni ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn kan ṣe ń pa àwọn ọmọ Yorùbá. Láìpẹ́ yìí ló kìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ kí wọn fi Sunday Ìgbòho lọ́rùn sìlẹ̀.