Categories
Ìròyìn

Sòwòrẹ́ Ní Kí Àwọn Ọmọ Nàíjíríà Dá Buhari Padà Sílé Láti London

YBTC News YORÙBÁ— A-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ-ènìyàn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọmọyẹlé Ṣòwò rẹ̀ ti ké sí àwọn ọmọ Nàíjíríà tí ó ń gbé ìlú Òyìnbó,London pé kí wọn dá ààrẹ Mùhámádù Buhari padà wá sí Nàìjíríà.

Buhari ló fí orilẹ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ sí London ní àná ọjọ́ Ìṣẹ́gun fún àyẹ̀wò àlàáfíà ara rẹ̀. Tí ilé iṣẹ́ ààrẹ sì jẹ́ kí á mọ̀ pé ààrẹ yóò padà sí orílẹ̀-èdè yìí ní ọ̀sẹ̀ Kejì oṣù kẹẹrin.

Ṣùgbọ́n Sòwòrẹ́ ti takò ìgbésẹ̀ ààrẹ yìí. Ó ní kí àwọn ọmọ Nàíjíríà ó dá a padà sí ilé láti wáá ṣe àtúnṣe sí ọ̀rọ̀ ìwòsàn orilẹ ede yìí dípò lílọ sí ilẹ̀ òkèèrè. Ó ní ètò ìṣe ìjọba Buhari kò dára rárá.

Gbogbo èyí ni Sòwòrẹ́ kọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ wípé kí wọn dá Buhari padà sí ilé.