Categories
Ìròyìn

Orí Ìbùsùn Ni Mo Ti Bá Ìyàwó Mi Pẹ̀lú Ọkùnrin Mìíràn – Ọkọ Ìyàwó

YBTC News YORÙBÁ— Alága ìgbìmọ̀ alábẹṣékélé ẹgbẹ́ ọlọ́kadà ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ti sàlàyé fún ilé ẹjọ́ abẹ́lé tí ó kalẹ̀ sí ilé tuntun ní ìlú ìbàdàn wípé àgbèrè ṣiṣe ìyàwó òun tí kọjá àfaradà.

Arákùnrin ọ̀hún, Jimoh Falọlá sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí ó ń fèsì sí ẹjọ́ ìkọni-sílẹ̀ tí ìyàwó rẹ̀, Ọpẹ́yẹmí,ẹni tí wọn ti fẹ́ ara wọn fún ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, gbé lọ sí ilé ẹjọ́.

Jimoh ni “Oluwa mi, ìwà àgbèrè ìyàwó mi ti di àìsàn inú ọkàn sími lára. Ọlá ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ọ̀rẹ́ ló ń jẹ. Òun ni mo fẹ́ràn jùlọ nínú àwọn ìyàwó mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí mo fẹ́, kò sí ohun tí ó béèrè tí mi ò níí fún-un.

Ọpẹ́yẹmí, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ fún adájọ́, ó ní ó dun òhun wípé ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n gbáko ni òun ti fi sòfò ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ Jimoh, ó ní ó ti sọ òhun di àpò ẹ̀ṣẹ́ nínú ilé.

Nígbà tí adájọ́ náà ń dájọ́, ó ní kí àwọn méjèèjì mú ẹ̀rí tó jinlẹ̀ dáadáa wá. Ó rọ̀ wọ́n kí wọn ní sùúrù fún ara wọn nítorí àwọn ọmọ wọn. Ní ìparí, ó sún ìgbà náà sí ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹẹrin ọdún yìí.