Categories
Eré Ìdárayà

Super Eagles Gbomi Lójú Benin, Wọn Pegede Fún Ife Adúláwọ̀

YBTC News YORÙBÁ—  Àwọn gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Super Eagles tí lọ lu àwọn akẹgbẹ̀ wọn ní orílẹ̀ èdè Benin nínú kòmẹsẹ̀yọ ìfẹ́ ilẹ̀ adúláwọ̀.

Ṣáájú ìdíje náà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí pegedé fún Ife ilẹ̀ adúláwọ̀ nígbà tí àwọn akẹgbẹ́ wọn tó kù, Lesotho àti Sierra Leone gbá ọ̀mì ẹ lẹ́yìn.

Super Eagles Nàìjíríà ti ń kọ ìtàn tuntun gẹ́gẹ́ bí wọn kò tíì fìdí rẹmi nínú kòmẹsẹ́yọ náà. Bákan náà ni wọn ba ìtàn orílẹ̀ èdè Benin jẹ́ pẹ̀lú bí wọn kò tíì lù wọ́n mọ́ ilé láti bíi ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn.

Ọ̀mì ni wọn gbá títí nínú ìdíje náà kí akọ́nimọ̀ọ́gbá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Genert Rohr tóó gbé Onuachu wọlé tí ó sì kan àmì ayò kan dodo inú ìdíje náà wọlé ní ó kù díẹ́ kí ìdíje náà wá sópin.