Categories
Ìròyìn

Ìbẹ̀rù Bo Ọ̀ṣun, Ènìyàn Mẹ́ta Kú Níbi Ìkọlù Àwọn Ẹlẹ́gbẹ́ Òkùnkùn

YBTC News YORÙBÁ— Ènìyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù láàrin àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ní agbègbè Kọ́láwọlé, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Èyí sì ti fa inú-fu-àyà-fu láàrin àwọn ènìyàn.

Ìròyìn fi tó wa létí pé ìkọlù náà wáyé láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aiye ati ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ àáké. Wọ́n ń jà fún ìfagagbága láti mọ ẹni tó lágbára jù nínú àwọn méjèèjì.

Àwọn tí ìkọlù náà sojú wọn sọ pe àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn náà dojú kọ ara wọn ní òwúrọ̀ òní ọjọ́ Àìkú pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìjà bíi ààmáke, àdá, ìbọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Níbi ìkọlù náà, àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn mẹ́ta ni a gbọ́ pé wọn pàdánù ẹ̀mí wọn ní àwọn agbègbè Kọ́láwọlé, Alie ati Ọbáléndé.

Ọ̀rọ̀ náà di bóòlọ-o- yàámi láàrin àwọn tó ń gbé agbègbè náà bí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ṣe ń fi ìbọn lé ara wọn kiri àdúgbò