Categories
Ìròyìn

Wọ́n Ti Bèèrè Fun N50m Owó Ìtúsílẹ̀ Àwọn Ọmọ Ìjọ RCCG

YBTC News YORÙBÁ— Àwọn ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ tí ìròyìn gbé wípé àwon ajínigbé agbébọn gbé ni a gbọ́ wípé wọn ti bèèrè owó tó tó N50m láti fi tú wọn sílẹ̀.

Olórí àgbà ijọ́ náà kan tí ó jẹ́rí sí ìlè àwọn ajínigbé yìí àti iye owó tí wọn bèèrè . Ó sàlàyé wípé déédé aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ alẹ́ àná nígbà tí wọn ń lọ sí ilé ìjọsìn.

Ẹ rántí wípé onímọ̀ ẹ̀rọ, ọ̀gbẹ́ni Eje Kenny Faraday láná ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìsẹ̀lẹ̀ náà ní alẹ́ àná ọjọ́ Ẹtì nígbà tí ó fi àwòrán ọkọ̀ náà hàn. Ó ní ọ́hun kó òun náà yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

A gbọ́ wípé àwon àgbà ìjọ ni àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ó wà nínú ọkọ̀ náà nígbà tí wọn ń lọ sí Kafanchan láti Kaduna.