Categories
Ìròyìn

Gbenga Daniel Sọ Ìdí Tí Ó Fi Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ APC

YBTC News YORÙBÁ— Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn ní ìgbà kan rí, Ọ̀túnba Gbenga Daniel, ti sọ ìdí pàtàkì tí òun fi dara pọ̀ mọ́ egbé òṣèlú APC, ó sàlàyé pé ìdí ni pé àsàyàn pọ̀ nínú ẹgbẹ́ náà.

Ó sọ èyí lẹ́yìn tí ó parí ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Mùhámádù Buhari ní ọjọ́ Ajé. Ó pàrọwà fún àwọn ènìyàn kí wọn ó gbé òṣèlú ẹ̀ta-inú jù sílẹ̀, kí wọn ó dara pọ̀ mọ́ ìṣèjọba gidi.

Ó ní lóòótọ́ ni orílẹ̀-èdè yìí ń dojú kọ onírúurú ìdojúkọ bíi ọrọ̀ ìlera, ọrọ̀ ajé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n, kò yẹ kí á máa fí eléyìí ṣe òṣèlú ní àsìkò tí a wà yìí.

Bákan náà ló mẹ́nuba ohun tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń sọ kiri wípé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń ṣa àwọn èèyàn sàǹkò-sàǹkò kiri láàrin ìlú sí inú ẹgbẹ́ wọn, wọ́n fẹ́ẹ́ sọ orílẹ̀-èdè yìí di ẹlẹ́gbẹ́ kan.

Ó ní, eléyìí kìí ṣe ọ̀rọ̀, PDP náà ti ṣe irú èyí darí lásìkò tí wọn ń darí orílẹ̀-èdè yìí.Àti wípé gbogbo ẹgbẹ́ ló ní ẹ̀tọ́ láti máa wá ọmọ ẹgbẹ́ kúnra.