Categories
Eré Ìdárayà

Man Utd Dáná Sun Westham, Juve Ju Cagilari Sí Kòtò

YBTC News YORÙBÁ— Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United ní alẹ́ òní fi àgbà hàn akẹgbẹ́ wọn, Westham United ní pápá ìṣeré wọn, Old Trafford, èyí ni ìdíje tí ó kẹ́yìn lónìí.

Ọ̀kan nínú agbábọ́ọ̀lù Manchester United, Mc Tominay ló kárí mọ́ bọ́ọ̀lù tó wá láti igun. Ṣùgbón lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnifínni, wọ́n ní ọmọ ilé Westham náà ló kàn án wọlé fún rarẹ̀.

Bákan náà ẹ̀wẹ̀ ní líìgì Seria A, gbajúgbajà ìlúmọ̀ọ́kọ́ agbábọ́ọ̀lù nnì, Cristiano Ronaldo ló dáná sun àwọn akẹgbẹ́ wọn, Cagilari, ayò mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló gbá wọlé wọn ní abala àkọ́kọ́.

Ní abala Kejì ni Simeone láti Cagilari náà dá ọkàn padà tí ìdíje náà sì parí sí mẹta sí ọ̀kan. Ní báyìí, ẹgbẹ́ Juventus wà ní ipò kẹta ní b’n líìgì Seria A.