Categories
Eré Ìdárayà

Arsenal Yẹ̀yẹ́ Tottenham, Ojú Mourinho Pọ́n, Ó fẹ́ẹ́ ké

YBTC News YORÙBÁ— Ìdíje líìgì Gẹ̀ẹ́sì ń tẹ̀síwájú ni ìrọ̀lẹ́ òní ojọ́ Àìkú ní pápá ìṣeré ńlá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, Emirate. Láàrin Arsenal àti akẹgbẹ́ wọn Tottenham.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Tottenham èyí tí olùkọ́ni Jisẹ Mourinho ló kọ́kọ́ rí àwọ̀n he, ní iṣẹju kẹrìnlálọ́gọ́ta láti ọwọ́ Eric Lamela, pẹ̀lú góòlù àràǹbarà tí ó gbá wọlé.

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Tottenham dà gẹ́gẹ́ bíi etí àkọ́kọ́ gbá ni, nígbàtí Arsenal ti Mikel Arteta kó sòdí padà dá àmì ayò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ padà sí àwọ̀n Tottenham, èyí tó mú ojú akọ́nimọ̀ọ́gba wọn pọ́n.

Ní báyìí, Tottenham tí ó yẹ́ kí ó gùnkè lọ sí ipò kẹfà tí wọn bá jáwé olúborí sì wà ní ipò keje ní orí tábìlì, tí Arsenal sì wà ní ipò kẹẹ̀wá.