Categories
Ìròyìn

A ó Tún Gùn Lé Ìyanṣẹ́ Lódì Láìpẹ́ Tí Ẹ Ò Bá San Owó Àwọn Òṣìṣẹ́ Wa – ASUU Fohùn Sílẹ̀ Fún Ìjọba Àpapọ̀

YBTC News YORÙBÁ— Àjọ tó ń rí sí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Yunifasiti, ASUU, ti ké tantantan fún ìjọba àpapọ̀ lórí àìsàn owó òsùn àwọn òṣìṣẹ́ wọn wípé àwọn yóò tún gùn lé ìyanṣẹ́ lódì láìpẹ́.

Àwọn àjọ náà fi ẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà àti ọ́fíìsì ACF pẹ̀lú bí wọn ṣe ń fi ara ni àwọn òṣìṣẹ́ àwọn láì fún wọn ní owó oṣù wọn láàrin bíi oṣù méjì sí oṣù mẹwàá.

Alága ẹgbẹ́ ASUU ti ẹka ilé ìwé ńlá Ibadan, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Akínwọlé nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ sàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ ò tíì dá owó tí wọn yọ nínú owó àwọn òṣìṣẹ́ àwọn padà láti ọjọ́ yìí.

Ó tẹ̀síwájú pé ó lé ní ọgọ́rùn-ún olùkọ ilé ìwé gíga náà ti kò rí owó oṣù gbà. Ó ní pàápàá jùlọ àwọn olùkọ́ tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ kò ì tíì gba owo kankan láti oṣù Kejì ọdún tí ó kọjá.