Categories
Eré Ìdárayà

Everton Gba Àlejò Ọ̀ràn Nínú Ilé Wọn, Burnley Bọ̀ Wọ́n Bí Ẹja Tútù

YBTC News YORÙBÁ—Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Everton gba àlejò ọ̀ràn nínú pápá ìṣeré wọn, Goodison Park ní ìrọ̀lẹ́ òní, bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Burnley ṣe ká wọn mọ́lé tí wọn sì nàwọ́n ní méjì sí ẹyọkan.

Abala àkọ́kọ́, nígbà tí ìdíje náà wọ ìṣẹ́jú mẹ́tàlá ni Chris Wood gba ayò àkókó wọlé, tí McNeil sí fi èkejì lée ní ìsẹ́jú kẹrìnlélógun.

Nígbà tí ìdíje náà wọ ìsẹ́jú kejìlélọ́gbọ̀n ni Richarlison dá ọ̀kan padà nínú rẹ̀. Báyìí sì ní ìdíje náà ṣe parí tí Carlo Anceloti àti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lórí pápá bí àgùntàn tí òjò pa.

Everton sì wà ní ipò kẹfà báyìí lórí tábìlì líìgì Gẹ̀ẹ́sì létí tó jẹ wípé wọn ò bá ti bọ́ sí ipò kaàrún tí wọ́n bá jáwé olúborí ni.