Categories
Eré Ìdárayà

Bayern Bayé Werder Bremen Jẹ́, Madrid Finá Má Elche

YBTC News YORÙBÁ— Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bayern Munich ṣe ẹgbẹ́ Werder Bremen ní ṣìbásìbo sí inú ilé wọn. Àmì ayò méta sí oókan ni wọ́n fi nàwọ́n. Bayern sì wà ní òkè téńté tábìlì líìgì Bundesliga.

Atamétàsé wọn, Robert Lewandowski sì tún fi ìwé ìtàn titun balẹ̀ pẹ̀lú ayò tó gbá wọ inú àwọ̀n Bremen. Ó to wà ní ipò Kejì nínú àwọn tí ó gbá bọ́ọ̀lù wọlé jù nínú ẹgbẹ́ Bayern Munich.

Bákan náà ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀u Real Madrid to fi àgbà hàn akẹgbẹ́ wọn, Elche ni orí pápá ìṣeré Santiago Bernabeu, pẹ̀lú bí wọn ṣe nàwọ́n ní méjì sí oókan.

Elche ló kọ́kọ́ rí àwọ̀n je kí ó tóó di wípé Kareem Benzema, atamétàsé Real Madrid gbá àmì ayò méjì sínú àwọ̀n wọn.